Ṣegun Oni fẹsun ibo rira kan awọn oloṣelu lawọn ilu kan

Taofeek Surdiq, Adeo-Ekiti
Ọkan ninu aWọn oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP, Oloye Ṣẹgun Oni, ti sọ pe o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe awọn kan n fowo ra ibo ni awọn wọọdu kan ni Ọyẹ Ado-Ekiti atawọn ilu kan kaakiri ipinlẹ naa. Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to dibo rẹ tan ni Wọọdu kẹrin, Yuniiti kẹfa, ni Opopona Oriọlọdẹ, to wa ni agbegbe Ilogbe, niluu Ifaki-Ekiti, to wa ni ijọba ibilẹ Ọyẹ Ekiti, lo sọrọ naa.
Oni ṣalaye pe awọn aṣoju oun kan sọ pe awọn kan n fun awọn eeyan lowo niluu Ọyẹ ati Ado-Ekiti lati dibo fun awọn alatilẹyin wọn. O fi kun un pe akọsilẹ ti wa nipa iye ibo to wa nibẹ, nidii eyi, awọn ko ni i sọrọ titi ti ajọ eleto idibo fi maa gbe esi idibo agbegbe naa jade. To ba waa ta ko ara wọn tabi ti wahala kan ba wa nibẹ lawọn maa ṣẹṣẹ mọ igbesẹ to kan lati gbe lori eleyii.
Ṣẹgun Oni to de ibudo idibo ni nnkan bii aago mẹwaa kọja pẹlu iyawo rẹ ti awọn mejeeji jọ wọ aṣọ funfun sọ fawọn oniroyin pe ko si wahala kankan ni agbegbe ti oun ti dibo, ohun gbogbo lọ nirọwọrọsẹ ni.

Leave a Reply