Ṣeun Ẹgbẹgbẹ bẹbẹ ni kootu: Ẹ tu mi silẹ, awọn ọlọpaa ko lẹrii kankan

Kazeem Aderohunmu

Lẹyin to ti lo ọdun mẹta lọgba ẹwọn, nibi to ti n reti bi igbẹjọ rẹ yoo ṣe lọ, Ṣeun Ẹgbẹgbẹ tun ti fara han ni kootu ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ohun to si sọ ni pe ki wọn fi oun silẹ, awọn ọlọpaa ko ri ẹsun gidi kan ka si oun lẹsẹ.

Ẹsun ogoji ni wọn ka si i lẹsẹ, ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa yii, lo foju han ni kootu pẹlu awọn eeyan wọnyi; Oyekan Ayọmide, Lawal Kareem, Ọlalekan Yusuf ati Muyideen Shoyọmbọ.
Ninu oṣu, keji ọdun 2017, ni wọn kọkọ wọ ọ wa sile-ẹjọ giga kan l’Ekoo, niwaju Adajọ Olurẹmi Oguntoyinbo.

Ọdun kẹta ree ti Ẹgbẹgbẹ atawọn eeyan ẹ ti wa lọgba ẹwọn, ṣaaju asiko yii nile-ẹjọ giga kan l’Ekoo, nibi ti igbẹjọ ẹ ti n lọ lọwọ ti fun un ni beeli, ṣugbọn to kuna lati ri awọn eeyan ti yoo ṣoniduuro fun un.

Miliọnu marun-un ati oniduuro to ti di ọga patapata lẹnu iṣẹjọba ni wọn sọ pe ko lọọ wa wa, nibẹ gan-an niṣoro nla ti de ba a, ti ko sẹni to fẹẹ fokun ọgẹdẹ gun ọpẹ.

Ẹsun ti fi wọn fi kan an nigba naa ni pe o gbiyanju lati lu awọn Hausa to n ṣẹwo dọla ni jibiti. Wọn ni Ẹgbẹgbẹ ko ṣẹṣẹ maa ṣe e, wọn lo pẹ to ti n pa awọn Hausa to n ṣe paṣipaarọ owo ilẹ okeere lẹkun gidi kaakiri Eko.
Lati le fidi ẹsun ti wọn fi kan an yii mulẹ, awọn Hausa to n ṣẹ owo dọla bii ọgbọn ni wọn pade ẹ ni kootu lati waa jẹrii tako o.
Ṣugbọn lọjọ kẹfa, oṣu yii, ni ọkunrin to maa n gbe sinima jade yii bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn tu oun silẹ nitori ko si ẹri kan gboogi, ti ileeṣẹ ọlọpaa ri ka si oun lẹsẹ, paapaa bi Innocent Anyigor, ọlọpaa to wa nidii ẹsun ti wọn fi kan oun yii ṣe kuna lati fidi ododo ọrọ ọhun mulẹ pe oun lu jibiti ni tootọ.
Ṣa o, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ọrọ ti Ẹgbẹgbe atawọn eeyan sọ pe awọn ko ri ẹri kan ka si wọn lẹsẹ.
Agbẹjọro ẹ to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe o buru pupọ bi awọn ọrẹ ẹ ṣe sa fun un lasiko yii, ti gbogbo awọn elere atawọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti wọn maa n gba owo lọwọ ẹ paapaa ko tiẹ fẹẹ ni ohunkohun i ṣe papọ pẹlu ẹ mọ.

Igbẹjọ yoo tẹ siwaju lọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun yii, niwaju Adajọ Oguntoyinbo.

Leave a Reply