Ṣeun Kuti di afadura-jagun lahaamọ, Daddy G.O ni wọn n pe e bayii

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni beeyan ba n sare koun ma tẹ, bi ko ba si rọgbọn da si i ti ẹtẹ fi wọle, ere keeyan ma ku lo ku ti tọhun gbọdọ bẹrẹ si i sa. Eyi lo ṣe rẹgi pẹlu bi gbaju-gbaja onkọrin Afrobeat nni, Ṣeun Kuti, ti i ṣe ọmọ bibi agba ọjẹ olori Afro, Oloogbe Fẹla Anikulapo Kuti, ṣe sọ ara rẹ di afadura-jagun lakolo awọn ọlọpaa tile-ẹjọ ni ko ṣi wa na, wọn lọkunrin naa lo n lewaju awọn afurasi ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ wa lọhun-un, to n gbadura kikankikan fun wọn papọ, bo si ṣe fitara gbadura ọhun lo mu kawọn eeyan ho yee, ti inu wọn dun, ti wọn si fun un loye ẹsin tuntun, GO, iyẹn General Overseer, to duro fun alakooso agba ijọ Ọlọrun ni wọn n pe e bayii, ti wọn si fun un ni Bibeli kan lati le maa fi ọrọ Ọlọrun bọ awọn yooku, ko si maa ṣoluṣọ-aguntan wọn.

Ipo tuntun ti afurasi ọdaran naa bọ si lahaamọ yii ko ṣai ni awuyewuye ninu. Wọn lawọn afurasi ẹlẹgbẹ rẹ kan fari ga nigba ti wọn kọkọ gbọ pe wọn fi Ṣeun ṣe GO, ti wọn si sọrọ si i, amọ kaka ti Ṣeun iba fi munu bi ọkunrin naa, ko si fara ya, bii iru eyi to ṣe fun ọlọpaa kan nirona lọjọsi, to fi bẹrẹ si i fibinu gba ọlọpaa leti lai fi ti kaki ọrun rẹ pe, wọn ni niṣe ni Ṣeun bẹrẹ si i parọwa jẹẹjẹ sawọn tinu n bi, to ni ki wọn ma binu, ki wọn mu suuru, ati pe oun ṣetan lati fun wọn ni ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn Naira (N25,000) bi wọn ba ṣetan lati sinmi agbaja.

Eyi lo mu kawọn afurasi naa beere pe awọn gbọdọ kọkọ ri owo ọhun na, oju-ẹsẹ si ni Ṣeun ti bẹ awọn ọlọpaa to n ṣọ wọn pe ki wọn jẹ koun ba iyawo oun sọrọ lori aago, lo ba ni kobinrin naa ko owo ọhun wa. Wọn ni lẹyin tawọn araabi gbowo yii tan ni wọn pariwo ‘Daddy GO’ tuntun, ni wọn ba ṣeto aaye kan fun un lati jokoo si laarin wọn nibẹ.

Akọroyin Vanguard kan to ṣabẹwo si ahamọ SCIID ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii sọ pe niṣe ni Ṣeun fi Bibeli naa ha abiya lasiko to n lọ sọfiisi Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa Eko, DCP Waheed Ayilara, bo si ti ṣetan lọfiisi ọhun ni wọn tun da a pada si aaye rẹ laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun,Tusidee to lọ yii lawọn ọlọpaa Eko wọ Ṣeun rele-ẹjọ lori ẹsun pe o ṣakọlu si ọlọpaa kan nirona, lori afara Third Mainland bridge, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un yii.

Eyi lo mu ki ọga ọlọpaa patapata paṣẹ ki wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe e, ki wọn si ba a ṣẹjọ lori iwa ọyaju naa. Ọpọ araalu ni wọn dẹbi fun Ṣeun lori ẹrọ ayelujara latari iṣẹlẹ naa. Ile-ẹjọ Majisreeti kan ni Yaba ti wọn wọ afurasi naa lọ ti paṣẹ ki wọn fi i sahaamọ fun ọjọ meji, ki wọn si gba beeli rẹ, amọ nigba tawọn ọlọpaa tun rawọ ẹbẹ pe awọn o ti i pari iwadii awọn, tori awọn ti lọọ gbọn ile Ṣeun yẹbẹyẹbẹ, awọn si ri awọn aṣiri kan nibẹ to le ran igbẹjọ naa lọwọ, ile-ẹjọ tun peroda, wọn fi ọjọ mẹrin-in kun asiko ti Ṣeun yoo fi wa lahaamọ wọn ọhun.

Leave a Reply