Lọsan-an, Ọjọruu, Tọsidee, ni Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Oyọ yọju si awọn ọdo to n fẹhonu han ni agbegbe Iwo Road, niluu Ibadan, nibi to ti rọ awọn ọdọ yii lati fọwọ wọnu, ki wọn se suuru, o ni gbogbo wahala to n lọ naa loun maa yanju.
Awọn ọdọ ọhun la gbọ pe wọn n mura lati lọọ dana sun agọ ọlọpaa to wa ni Idi-Apẹ, ko too di pe gomina lọọ pade wọn ni Iwo-Road, lati dekun igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe naa.
Makinde to sọkale ninu mọto, to si fesẹ rin lọ saarin omilegbe awọn ọdọ naa lo ba wọn sọrọ o ni ohun to ba ti ba oju ba imu, ati pe ohun to ba kan wọn ti kan oun naa. Ṣugbọn ki awọn eeyan naa ni suuru, ki wọn gba alaafia laaye, ki wọn si ma fa wahala kankan.
O ṣeleri pe gbogbo awọn ọdọ ti awọn ọlọpaa ti mu to wa latimọle wọn loun maa gba jade ki ile ọjọ naa too su.
Nise ni inu awọn ọdọ yii dun, ti wọn si jọ n kọwọọrin lọ pẹlu gomina bi wọn ṣe n sa a, ti wọn n pe e ni ọkan-o-jọkan orukọ lati fi idunnu wọn han si i.