Ṣeyi Makinde sabẹwo ibanikẹdun si mọlebi obinrin ti Fulani darandaran ṣa ọmọ rẹ pa n’Igangan

Jide Alabi
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣabewo ibanikẹdun si idile awọn ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko tawọn Fulani darandaran n ṣoro bii agbọ ladugbo Ibarapa.
Ọkan ninu awọn mọlẹbi ti Makinde ṣabẹwo si ni Abilẹkọ Idowu Bababrinde, ẹni ti awọn Fulani darandaran yinbọn pa ọkan ninu awọn ọmọ rẹ.
Bakan naa ni gomina ni awọn tun ṣabẹwo sile Alaaji Azeez Aborode to jẹ baba fun Dokita Fatai Aborode tawọn Fulani pa nipakupa lasiko to n ti oko rẹ bọ laipẹ yii.
Gomina ba wọn kẹdun, o si ṣadura fun wọn pe Ọlọrun yoo rọ wọn loju.

Leave a Reply