Ṣeyi to n ṣiṣẹ nile tẹtẹ dana sun’ra rẹ n’Ikire

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin kan to n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ tẹtẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ṣeyi la gbọ pe o ti dana sun ara rẹ niluu Ikire, nipinlẹ Ọṣun.

Ṣe ni Ṣẹyi, ẹni ti ṣọọbu kekere to ti n ṣiṣẹ wa ni aarin-gbungbun ilu naa, ti ara rẹ mọnu ṣọọbu, to si dana sun ara rẹ mọbẹ.

A gbọ pe ko too di pe awọn ti wọn wa layiika naa mọ nnkan to n ṣẹlẹ, o ti jona kọja sisọ.

Ẹnikan to n gbe lagbegbe naa ti ko fẹ ka darukọ oun ṣalaye pe ṣe lawọn kan deede ri i ti eefin n jade latinu ṣọọbu Ṣeyi, ko si si ẹni to tete mọ pe ọmọkunrin naa wa nibẹ.

O ni niṣe lo tilẹkun ati ferese ṣọọbu naa nigba to fẹẹ dana sun ara rẹ nibẹ lai ba ẹnikẹni sọ ohun to n la kọja.

Ọkunrin yii fi kun ọrọ rẹ pe ko fi apẹẹrẹ kankan silẹ rara pe oun fẹẹ gbẹmi ara oun, koda, wọn lo fun ọmọ rẹ lowo ko too wa si ṣọọbu lọjọ naa, o si ti jona bajẹ ki wọn to gbe oku rẹ sita.

Ohun tawọn kan n sọ, ṣugbọn ti a ko le fidi rẹ mulẹ ni pe ọmọkunrin naa fi owo to pa nidii tẹtẹ, eyi to pọ niye to jẹ ti ọga rẹ ta tẹtẹ ni, nigba ti ko si jẹ, ti ko si mọ ọna to le gba da owo pada lo mu ko dana sun ara rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni bo ṣe ku ni awọn mọlẹbi rẹ ti gbe oku rẹ lọ, ko si si ẹni to fura si ohunkohun pe o le ṣokunfa igbesẹ ti ọkunrin naa gbe.

Leave a Reply