Adewale Adeoye
Ni bayii, afi k’awọn araalu tete yaa lọọ ra ounjẹ silẹ lọpọlọpọ, tori bi ọrọ tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii, ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC), ati ajọ ọlọja orileede yii ‘Trade Union Congress’ (TUC), n sọ ba jẹ ootọ, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni gbogbo awọn oṣiṣẹ ọba ati ti aladaani yoo bẹrẹ si i mọ iṣẹ loju tẹki, oloko ko ni i le roko, olodo ko si ni i le rodo, gbogbo ọna ọfiisi ati ileewe yoo da paroparo latari iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ ti wọn kede pe awọn yoo gun le jake-jado orileede Naijiria. Iyanṣẹlodi ọhun maa bẹrẹ lati ọganjọ oru ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Niṣe ni awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati ti olokoowo, TUC, Kọmureedi Joe Ajaero ati Festus Osifo, n tu bii ejo sebe tinu n bi lasiko ti wọn n sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lẹyin ipade pajawiri kan to waye laarin awọn aṣoju ijọba apapọ ati ti ẹgbẹ mejeeji naa.
Ajaero ni o ṣe pataki pupọ fawọn lati gun le iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ, ti ko ni gbedeke ìgbà ti wọn yoo jáwọ ninu rẹ naa nitori bi ijọba orileede yii ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ owo-oṣu tuntun tawọn n beere lọwọ wọn, ati owo ina ẹlẹntiriiki tawọn ni kijọba da pada si bọ ṣe wa tẹlẹ.
Aarẹ ẹgbẹ naa waa rawọ ẹbẹ sawọn araalu gbogbo ti igbesẹ wọn maa ni ipalara gidi fun pe ki wọn fọwọ wọnu, ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu awọn, nitori pe ija gbogbo araalu lawọn n ja.
O ni, ‘Mo mọ daju pe igbesẹ ta a fẹẹ gbe yii maa ṣakoba nla fawọn araalu kan, mo n bẹ wọn ni, pe ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu wa, ija ilu la n ja bayii, o si daju pe aa so eeso rere nigbẹyin ni. O ṣe pataki pupọ fun wa lati bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ naa bayii, kawọn alaṣẹ ijọba apapọ orileede yii le mọ pe a ko fọrọ naa ṣere rara, wọn ko da wa lohun awọn ohun taa beere lọwọ wọn gbogbo, a n fẹ owo-oṣu tuntun lọwọ wọn, wọn ko da wa lohun, bẹẹ la n sọ pe ki wọn da owo ina pada si bo ṣe wa tẹlẹ, wọn ko da wa lohun’. Gẹgẹ bi wọn ṣe wí.