Adewale Adeoye
Minisita fun eto inawo nilẹ wa, Wale Ẹdun, ti sọ pe ijọba apapọ maa too bẹrẹ si i fun awọn araalu, paapaa ju lọ, awọn mẹkunu ni ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin Naira gẹgẹ bii owo iranwọ ti wọn ṣeleri rẹ fun wọn laipẹ yii.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni minisita ọhun sọrọ naa di mimọ l’Abuja, lasiko to n jiyin iṣẹ iriju rẹ fun ti ayẹyẹ ọdun kan ti Aarẹ Tinubu gbajọba.
O ni awọn araalu tiye wọn to miliọnu mẹẹẹdogun jake-jado orileede yii ni wọn maa jẹ anfaani ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin Naira owo iranwọ ti wọn ṣeleri rẸ fun wọn laipẹ yii, ki ara baa le tu wọn fun bi ilu ṣe le koko bayii.
Ẹdun, to jẹ alaga igbimọ alabẹṣekele kan tijọba apapọ gbe kalẹ lati ṣeto iranwọ owo naa fawọn araalu ni eto ọhun ṣepataki pupọ fawọn araalu, paapaa ju lọ fawọn mẹkunu to jẹ pe agbara kaka ni wọn fi n rọwọ mu lọọ sẹnu lojumọ.
O ni, ‘‘Eto gidi ti wa nilẹ bayii lati ri i daju pe kaluku awọn ẹni to nilo owo naa ni wọn maa tẹwọ gba a lọwọ ijọba apapọ, ijọba si ti n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu pẹlu awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ kọọkan lati le jẹ ki eto naa yọri sibi to daa.
‘’Ṣa o, awọn ti wọn ba maa jẹ anfaani eto naa gbọdọ ni nọmba idanimọ NIN, wọn gbọdọ ni banki kan pato ti wọn n lo, tabi eyi ti wọn n lo nọmba foonu wọn fi ṣi lasiko yii, ki wọn baa le gbowo naa lọdọ ijọba, inu akaunti onikaluku nijọba maa fi owo ọhun ranṣẹ si, ki mago-mago kankan ma baa si nibẹ. Idile, tabi ki n sọ pe araalu ti wọn jẹ mẹkunu nijọba maa fun ni ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin Naira yii.
‘’Ki awọn araalu baa le ni igbẹkẹle ninu eto naa, a n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu pẹlu minisita eto ibanisọrọ ati ẹrọ ayelujara, ti eto ilera ati tawọn ọdọ, ‘Minister of Communication and Digital Economy, Health and Youth’ lorileede yii. Awọn naa ni iranlọwọ gidi ti wọn maa ṣe fun wa lori eto naa bo ba bẹrẹ ni pẹrẹwu. Ki awọn araalu lọọ ni awọn ohun ta a ka silẹ yii ko too di pe eto naa bẹrẹ.
Ọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024, ni Aarẹ Tinubu gbẹsẹ le eto owo iranwo naa lẹyin tawọn araalu fẹsun ikowojẹ ati ibajẹ kan minisita to wa nidii rẹ tẹlẹ.