Adewale Adeoye
Ẹsẹ ko gbero niwaju ileeṣẹ ijọba kan, ‘National Medical Services Laboratories’ to wa niluu Pennsylvania, lorileede Amẹrika, nibi ti wọn ni wọn ti ṣayẹwo s’okuu Oloogbe Mohbad lara lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii. Awọn ololufẹ gbajumọ akọrin nni, Oloogbe Ilerioluwa Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad, ni wọn ko ara wọn jọ lọ siwaju ileeṣẹ naa. Koko ohun ti wọn n beere fun lọwọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ni ojulowo abajade esi ayẹwo tileeṣẹ naa ṣe s’okuu Ilerioluwa. Wọn lawọn fẹẹ mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ.
ALAROYE gbọ pe lẹyin tawọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko kede esi ayẹwo ti wọn lawọn gba lati ileewosan naa, loju-ẹsẹ ni awọn alaṣẹ ileewosan naa ti ta ko ọrọ tijọba Eko sọ. Wọn ni ki i ṣe ọdọ awọn ni abajade esi ayẹwo tijọba Eko kede rẹ fawọn araalu ti wa.
Bẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Keji, ọdun yii, ni Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọshọ, fesi si ibeere kan ti atọkun eto kan beere lọwọ rẹ pe nibo gan-an ni wọn ba ayẹwo oku oloogbe naa tijọba ipinlẹ Eko n ṣe de, ti ọkunrin naa si fesi pe awọn n reti esi ayẹwo naa lati ileewosan ‘National Medical Services Laboratories’ (NMAS), to wa niluu Pennsylvania, lorileede Amẹrika ni.
Ṣugbọn nigba ti onimọ ijinlẹ nipa ayẹwo sokuu lara to jẹ aṣoju ijọba ipinlẹ Eko maa sọrọ nipa ayẹwo ọhun nile-ẹjọ kan niluu Ikorodu laipẹ yii, o sọ pe ileewosan ijọba tawọn ti lọọ ṣayẹwo s’okuu oloogbe naa lara l’Oke-Okun ko le fidi ohun to pa a mulẹ, nitori pe oku rẹ ti n jẹra lasiko tawọn lọọ hu u jade nibi ti wọn sin in si.
Ṣugbọn awọn ile ayẹwo ti wọn darukọ niluu oyinbo ni ki i ṣe ọdọ awọn nijọba ipinlẹ Eko ti waa ṣayẹwo s’okuu oloogbe naa, nitori awọn ko foju kan wọn.
Ọrọ naa lo mu ki lọọya ẹbi oloogbe atawọn ololufẹ ọmọkunrin yii fajuro gidi si bi awọn alagbara kan ṣe fẹẹ fọwọ bo ootọ mọlẹ nipa ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa.
Lọjọ Aje, Mọnnde, ọsẹ yii lawọn ololufẹ oloogbe naa kan l’Oke-Okun kora wọn jọ, ti wọn si gba iwaju ileeṣẹ ijọba ti wọn ni ibẹ ni wọn ti ṣe ayẹwo naa lọ. Koko ohun ti wọn n beere fun ni pe ki wọn so eyi to n jẹ ootọ nipa ayẹwo naa.