Faith Adebọla
Lasiko yii, makan-makan loye n kan lọrọ iyansipo ati didi ipo oṣelu mu jẹ fawọn gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa pẹlu bi ọkọọkan ijọba ṣe n yan wọn sawọn ipo pataki lawọn ipinlẹ ati ni olu-ilu wa, Abuja.
Lọtẹ yii, ẹni ti ilẹkun oriire naa ṣẹṣẹ ṣi fun, ti iroyin rẹ si ti n ja ranyin kaakiri ni ilumọ-ọn-ka oṣerebinrin to lomi lara daadaa nni, Ẹniọla Badmus, tawọn eeyan mọ si Wule Bantu tabi Gbogbo Big Gẹs. Wọn ti yan an sipo Oludamọran pataki si Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Ọnarebu Tajudeen Abbas.
Ninu fidio kan ti Ẹniọla gbe sori ayelujara lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lo ti ṣafihan bi olori awọn aṣofin naa ṣe n fi lẹta iyansipo rẹ le Ẹniọla lọwọ, ti ariwo gee si tẹle e, pẹlu bawọn ololufẹ rẹ ṣe n ki i kuu oriire, ti wọn n ṣe kọngiratuleṣọn ni mẹsan-an mẹwaa. Bawọn kan ṣe n bọ ọ lọwọ, bẹẹ lawọn mi-in n di mọ ọn, ti wọn n gba a mọra, ti wọn si n ba dawọọ idunnu.
Lẹta iyansipo naa sọ pe ọrọ lori ariya ati ifitonileti araalu ni Ẹniọla Badmus yoo maa ṣeranlọwọ fun Tajudeen Abass le lori, iyẹn Special Assistant on Social Events and Public Hearings. Lẹyẹ-o-sọka si ni iyansipo naa ti bẹrẹ iṣẹ.
Ẹ oo ranti pe laipẹ yii ni iru oriire yii de ba arẹwa oṣerebinrin ilẹ wa kan, Laide Bakare, nigba ti Gomina ipinlẹ Ọṣun yan an sipo oludamọran pataki ninu iṣejọba rẹ.
Lara awọn oṣere lọkunrin lobinrin to ti lo saa nipo oṣelu ni Abdul-Gafar Abiọla, tawọn eeyan mọ si Cute Abiọla, Fẹmi Adebayọ, ti wọn tun n pe ni Jẹlili Oniso, Eyiwunmi Aramide, ti wọn n pe ni Muka Ray, bo si ṣe n ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere ilẹ Yoruba, bẹẹ lawọn oṣere elede oyinbo naa n gbadun anfaani ati iyansipo bẹẹ.
Ṣa, Ẹniọla Badmus lọmọ ti wọn n sọ lọwọ yii, orukọ rẹ ko si ni i bẹrẹ pẹlu Ẹniọla ṣakala mọ, amọ Ọnarebu Ẹniọla Badmus ni lasiko yii.