Ọrẹoluwa Adedeji
Nibi tọrọ de duro bayii, Ọlọrun nikan lo le ko ọmọkunrin to maa n mura bii obinrin nni, Idris Okunnẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisy yọ ninu wahala tuntun to wa bayii. Ba a ṣe n kọ iroyin yii, ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa ti fi ọmọkunrin naa ṣọwọ si ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran, iyẹn Federal Criminal Investigative Department, to wa ni Alagbọn, nipinlẹ Eko. Nibẹ lawọn ọlọpaa ti n fọrọ po o nifun pọ lori ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ lori bi wọn ṣe ni ọmọkunrin ti wọn tun n pe ni Mummy of Lagos yii ṣe sa kuro niluu Eko, to si fẹẹ sọda si ipinlẹ Bẹnnẹ, ki wn too da a duro ni Sẹmẹ bọda.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ni wọn gbe lati Sẹmẹ boda, nibi to sun mọju, wa si Alagbọn inu galagala wọn lo si sun mọju ọjọ Aje si ọjọ Iṣegun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Alagbọn, Aminat Mayegun, fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni Bobrisky wa lọdọ awọn. O ni, ‘’O wa lọdọ wa, a si ni lati tọju rẹ si ahamọ lonii’’.
Ṣaaju ni Alukoro ileeṣẹ aṣọbode, Kenneth Udo ti sọ pe ohun to fa a ti awọn fi mu Okunnẹyẹ ni pe o jẹ ẹni ti wọn fẹẹ ba ni gbolohun lori awọn ọrọ to ti wa nilẹ.
Nibi tọrọ de duro bayii, afaimọ ki ọmọkunrin naa ma tun ba wọn lalejo ninu ọgba Kirikiri lẹẹkan si i.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ogunjọ, oṣu yii ni awọn aṣobode da a duro ni bọda Sẹmẹ, nigba to n gbiyanju lati kọja si orileede Bẹnnẹ.
O jọ pe wahala ti ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Verydarkman da si i lọrun lo fẹẹ tori ẹ sa kuro ni Naijiria. Fọnran kan ni ọkunrin naa gbe sori ayelujara, nibi ti Bobrisky ti n ni itakurọsọ pẹlu ẹnikan, to si sọ pe oun san miliọnu mẹẹẹdogun Naira fun aọn oṣisẹ EFCC kan, ki wọn le yọ ọran ṣiṣẹ arọndarọnda owo kuro lọrun oun. Bẹẹ lo tun ni oun fun awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn ni owo ki oun mabaa sun ninu ọgba ẹwọn lasiko ti wọn fi ran an lewọn.
Bakan naa lọrọ ọhun ta ba agbẹjọro ilẹ wa nni, Fẹmi Falana ati ọmọ rẹ, Fọlarin, ti Bobrisky ni oun bẹ lọwẹ si baba rẹ, ko le ba oun ṣeto bi oun yoo ṣẹ gba idariji Aarẹ, eyi ti wọn n pe ni presidential pardon.
Gbogbo ọrọ yii lo ti n ja ranyin nilẹ, tiu Minisita fun ọrọ abẹle nilẹ wa si gbe igbimọ dide alti ṣewadii rẹ.
Ni ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kọkanlelogun ni igbimọ naa jade pe ko si ẹri lati fi han pe Bobrisky ko sun ọgba ẹwọn naa gẹgẹ bi wọn ṣe fẹsun kan an.
Ni bayii, Alagbọn ni Mummy of Lagos wa ti awọn ọlọpaa ti n fọrọ po o nifun pọ lori bo ṣe fẹẹ sa kuro nilẹ wa.