Ṣọla Agboọla n lọ sẹwọn ba a ti kọwe rẹ, ẹsun idigunjale ni wọn fi kan an

Faith Adebọla, Eko

 

 

“Gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ yii lo fidi ẹ mulẹ, ko si si iyemeji nibẹ rara pe adigunjale han-ran-un ni ọ, ati pe o jẹbi ẹsun idigunjale. Nitori naa, idajọ mi niyi, ile-ẹjọ yii sọ ọ si ẹwọn ọdun mọkanlelogun pẹlu iṣẹ aṣekara.”

Bayii ni Adajọ Hakeem Oṣhodi ṣe kede fun Ọgbẹni Ṣọla Agboọla lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko. Ẹsun mẹta ọtọọtọ ni olujẹjọ naa n jẹjọ rẹ, bo ṣe wa ninu iwe ẹsun ti nọmba rẹ jẹ ID/706c/14.

Lara ẹsun naa ni pe o digunjale, o gbimọ-pọ lati digunjale, wọn si tun lo ṣakọlu sawọn ẹni ẹlẹni meji kan lasiko to n ja wọn lole. Lati ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ, ọdun 2014, ni wọn si ti wa lẹnu ẹjọ naa.

Agbefọba, Ọlabisi Ogungbẹsan, to wa lati ẹka to n ṣeto igbẹjọ araalu (Directorate of Public Prosecution) ẹka ti Eko, lo ti kọkọ rọ ile-ẹjọ pe lati gbe idajọ rẹ kale nibaamu pẹlu bawọn ẹlẹrii mẹrin ti olupẹjọ ko kalẹ ṣe jẹrii ta ko olujẹjọ, ti olujẹjọ naa ko si ri ẹri kan mu wa lati gbeja ara rẹ, to jẹ mẹin-mẹin lo n ṣe.

Ọlabisi ni ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ naa ta ko isọri kejilelaaadọsan-an (172), isọri ọọdunrun o din marun-un (295) ati ọọdunrun o din mẹta (297) ninu iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2015 nipinlẹ Eko.

Adajọ Oshodi ni ki Agboọla lọọ ṣẹwọn ọdun meje fun ọkọọkan awọn ẹsun mẹta to jẹbi rẹ, aropọ ẹwọn rẹ si jẹ ọdun mọkanlelogun, bo tilẹ jẹ pe latigba ti igbẹjọ rẹ ti bẹrẹ ni wọn yoo ti maa ka ẹwọn rẹ fun un, ẹẹkanaa si ni wọn yoo ṣẹwọn ẹsun mẹtẹẹta.

Leave a Reply