Ṣoworẹ gbe awọn oloṣelu to n ra ẹrọ ata faraalu ṣepe

Ọlawale Ajao, Ibadan

Oludije fun ipo aarẹ orileede yii lorukọ African Action Congress (AAC), Ọgbẹni Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ti ṣapejuwe owo ati oriṣiiriṣii ẹbun tawọn oloṣelu maa n pin fawọn araalu gẹgẹ bii ọna lati da kun iṣẹ atoṣi to wa laarin awọn mẹkunnu.

Nibi apero ti awọn igbimọ to n ja fun idagbasoke ẹkun Iwọ-Oorun Guusu ilẹ yii, iyẹn South-West Development Stakeholders Forum, gbe kalẹ fawọn to n dupo aarẹ ilẹ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, lo ti sọrọ naa ni gbọngan Jogor Centre, n’Ibadan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ko ni i ragba fun gomina to n pin ẹrọ ata, to n pin ẹgbẹrun mẹwaa, mẹwaa Naira faraalu. Ẹni to sọ pe oun fẹẹ mu idagbasoke ba eto ọrọ aje, to n pin ẹrọ ata, to n pin tẹn taosan, ki ni iru nnkan bẹẹ fẹẹ tun ṣe ninu eto ọrọ aje to ti bajẹ.

“Awọn Yooba maa n powe pe ile to ba n toro, ọmọ ale ibẹ ni ko ti i dagba. Ṣẹẹ ri i, awọn ọmọ ale Yoruba ti di anbasadọ si Abuja, wọn ti di Yahoo to n ko owo yin jẹ. Tẹ ẹ ba ni kẹ ẹ dibo fun awọn ti ko ka ọrọ Naijiria si, a ṣẹṣẹ bẹrẹ iya ni o.

“Ẹ ṣaa mọ baba to wa l’Ọta, ọdun mẹjọ ni wọn lo nipo ti wọn ko le se titi Eko si Ọta. Iru ọna Ibadan si Eko ti wọn fi ogun ọdun ṣe yẹn, awa a a ṣe e laarin oṣu mẹfa. Ọkọ oju irin tiwọn to n fa bii igbin, awa aa ṣe eyi ti yoo maa yara rin”.

O waa ṣeleri lati pese eto aabo, ilera ọfẹ, ẹkọ ọfẹ ati eto igbaye-gbadun fun gbogbo ọmọ Naijiria bi oun ba wọle idibo sipo aarẹ ilẹ yii.

Bẹẹ lo ni ijọba oun yoo pese ofin tuntun forilẹede yii, nitori ọpọlọpọ aiṣedede lo wa ninu ofin ọdun 1999 ti Naijiria n lo lọwọ.

Ṣaaju lọkan ninu awọn igbimọ to ṣagbekalẹ eto naa, Dokita Muyiwa Bamgbose, ti sọ fun oludije funpo aarẹ naa loju gbogbo aye pe awọn ko tori owo gbe eto naa kalẹ, nitori naa, awọn ko beere owo tabi gbowo lọwọ eyikeyii ninu awọn oludije to kopa nibi eto yii bi ko ṣe pe ki kaluku ba ara wọn sọ ootọ ọrọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Alao Adedayọ, alaga igbimọ to ṣagbekalẹ eto naa, sọ pe “a mọ-ọn-mọ ma pe awọn lọbalọba atawọn eeyan to lookọ lawujọ sibi eto yii ni, awọn eeyan wa, awọn iyalọja, iyalaje, oniṣẹ ọwọ, oniṣowo ati bẹẹ bẹẹ lọ la pe lati waa fojurinju pẹlu awọn to n dije dupo aarẹ.

“A n ṣe eyi ki ẹyin araalu le mọ pe ẹyin naa ni ipa lati ko ninu ọrọ idagbasoke orileede yii, paapaa, ilẹ Yoruba tiwa nibi.”

Adedayọ, to jẹ oludasilẹ iweeroyin ALAROYE fi kun un pe “kaadi idibo yin lagbara yin. Gbogbo awọn oloṣelu atawọn eeyan nla nla ti ẹ n ri laduugbo yẹn, ibo kan lawọn naa ni, kaadi kan ni wọn ni, ẹni tẹ ẹ ba ri kaadi pupọ lọwọ ẹ, ọdaran ni.

 

Leave a Reply