Ṣoyinka parọwa sijọba Bẹnẹ: Ẹ fi Sunday Igboho lọrun silẹ o, ẹ jẹ ko maa ba irinajo ẹ lọ  

Nibi ipade awọn oniroyin kan to waye ni ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni ogbontarigi onkọtan ati ọmọwe nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti parọwa sijọba orileede Olominira Benin pe ki wọn tu eekanna lẹyin ọrun gbajugbaju ajijagbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, to ti wa lahaamọ wọn, o loun o ri ẹsun tabi ẹṣẹ pato kan ti wọn mu ọkunrin naa sahaamọ fun.

Ṣoyinka sọrọ yii lọfiisi rẹ niluu Eko, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Ọkunrin naa ni ko si idi kan pato ti wọn tori ẹ mu Sunday Igboho sahaamọ, o ni ko huwa ọdaran kan, ko si si ẹsun to lagbara kan ti wọn ka si i lẹsẹ.

“Mi o le gbagbọ pe Sunday Igboho dẹṣẹ kan ju pe o sọrọ ta ko bawọn ọbayejẹ Fulani ṣe n ṣakọlu sawọn eeyan rẹ lọ. Jẹẹjẹ lo si maa n ṣe iwọde rẹ lati fi ero rẹ han. Ki lo waa buru ninu iyẹn, mi o ri iwa ọdaran kan ninu ohun ti Sunday Igboho ṣe.

Ti pe o loun o fẹ kawọn eeyan oun ba Naijiria ṣe mọ, pe oun fẹ ka daro ni, iyẹn ki i ṣe ẹṣẹ, ko si siwa ọdaran kan ninu ohun to ṣe. Keeyan loun o fẹẹ ba orileede kan lọ mọ ki i ṣe ẹṣẹ, niwọn igba ti tọhun ba ti n beere wọọrọwọ lai fa ijangbọn kan.”

Ṣoyinka ni oun parọwa sijọba orileede Bẹnẹ atawọn agbofinro wọn lati yọ okun lọrun Sunday Igboho, ko le maa ba irinajo rẹ lọ.

Ṣe lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ agbaye kan ti fi pampẹ ofin mu Sunday Igboho ati iyawo rẹ, Rọpo, ni papakọ ofurufu to wa niluu Cotonou, wọn ni wọn lufin immigireṣọn awọn, ṣugbọn lọjọ keji ni wọn ti fi iyawo naa silẹ, lẹyin ti wọn ti foju wọn bale-ẹjọ, latigba naa si ni Ọgbẹni Sunday ti wa lakata wọn.

Leave a Reply