Ṣaja ti Titilayọ gbagbe sibi to ti lọọ ṣaaji foonu lo lọọ mu ti Musa fi fipa ba a lo pọ n’Ibadan

Faith Adebọla

Ile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ siluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ti paṣẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ yii, pe ki wọn ṣi tọju afurasi ọdaran ẹni ogun ọdun kan, Musu Sulaimon, sahaamọ ọgba ẹwọn Agodi, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ba ọmọbinrin ọmọọdun mejidinlogun, Titilayọ Sunday, laṣepọ, nigba tiyẹn gbagbe ṣaja foonu ẹ si yara ọrẹ Musa.

Agbefọba, Oluṣẹgun Adegboye, to ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ ni kootu sọ pe ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ta a wa yii niṣẹlẹ naa waye.

Wọn ni ọrẹ Musa kan lo n gbe adugbo Oriyangi, ni Ogbere, niluu Ibadan, adugbo yii naa si ni ọmọbinrin yii n gbe pẹlu awọn obi rẹ, ṣugbọn ki i ṣe ile kan naa.

Lọjọ iṣẹlẹ yii, Titilayọ ti lọọ ṣaaji foonu rẹ nile ọrẹ Musa yii, nigba to si pada waa mu foonu naa, ko ranti yọ ṣaja rẹ, o gbagbe ẹ sinu ile naa.

Ṣaja yii lo ni koun pada lọọ mu lọwọ irọlẹ, ni nnkan bii aago mẹrin naa. Musa lo ba nile aladuugbo rẹ, o si ṣilẹkun fun un. Bi ọmọbinrin naa si ti wọ yara lati mu ṣaja to gbagbe, niṣe ni Musa tilẹkun mọ ọn, to fipa wọ ọ sori aga timutimu, lo ba fipa ba a laṣepọ.

Ṣugbọn ma ṣe e, loogun ma mọ ọn, akara ọrọ naa pada tu sepo, nigba tọrọ detiigbọ awọn ọlọpaa, ọwọ ba Musa lẹyin tawọn ọtẹlẹmuyẹ ṣewadii, to si han pe loootọ lafurasi yii ṣe ‘kinni’ tipatipa fọmọọlọmọ, lọrọ ẹ fi de kootu.

Wọn lẹsun naa ta ko isọri ọtalelọọọdunrun din mẹta (357) ati ọtalelọọọdunrun din meji (358) iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2000 nipinlẹ Ọyọ.

Lẹyin ti wọn ti ka ẹsun naa si olujẹjọ yii leti tan, Adajọ O. A. Ẹnilọlobọ to jẹ alaga kootu naa ni ẹsun ti wọn ka silẹ yii kọja agbara ile-ẹjọ Majisreeti oun, o ni ki wọn da faili ẹsun naa pada sọdọ ileeṣẹ to n gba adajọ nimọran lori awọn ẹsun bayii, ki wọn le pinnu ile-ẹjọ to yẹ lati gbọ ẹsun ifipabanilopọ ati iwa ọdaran ti wọn fi kan afurasi yii.

O ni ki wọn la Musa mẹwọn Agodi titi dọjọ igbẹjọ mi-in lẹyin tawọn ba ti ri amọran DPP gba.

Leave a Reply