Ṣe asasi waa leleyii ni abi eedi, Pele Onikoko si pokunso sinu ṣọọbu rẹ niluu Gbọngan

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ko sẹni ti ko mọ Pele Onikoko niluu Gbọngan nipinlẹ Ọṣun, yatọ si pe Ọlọrun fi buruji diẹ ta a lọrẹ, o tun jẹ eeyan takuntakun ninu ijọ St Peters Anglican Church to n lọ. Idi niyi ti iku rẹ fi jẹ kayeefi fawọn eeyan ilu naa nigba ti wọn gbọ pe o pokunso lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.

Festus Ọlawale Ayandokun gan-an ni orukọ rẹ, ọmọ mẹrin lo bi, o si ni iya laye. Ṣe lo wọnu yara kekere kan to wa lara ṣọọbu koko (cocoa store) rẹ ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa, lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn ko gburoo rẹ ni wọn yọju wo ibi to wa.

Ṣe ni wọn ba a to ti fi okun ifami so ara rẹ mọ aja ile naa, to si ti n mi dirodiro. Aarọ ọjọ Satide ni awọn oloro ja oku rẹ lẹyin etutu, wọn si lọọ sin in sile rẹ to wa ni agbegbe Wakajaye, ni Express, ilu Gbọngan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ALAROYE, o ni ẹni ọdun mẹtalelogoji ni Pele, ati pe iwadii ti bẹrẹ lori iku ẹ.

 

One thought on “Ṣe asasi waa leleyii ni abi eedi, Pele Onikoko si pokunso sinu ṣọọbu rẹ niluu Gbọngan

Leave a Reply