Ṣe awọn baba wa nilẹ Yoruba ṣe aṣiṣe ni? (10)

ỌMỌ ỌDỌ AGBA

Nigba ti asiko idibo ba n bọ bayii, awọn ti wọn n pe ara wọn ni aṣaaju Yoruba, wọn aa si pin si yẹlẹyẹlẹ. Awọn kan aa gba iwaju, awọn kan aa gba ẹyijn, awọn kan aa gba aarin, awọn kan aa gba ọtun, awọn kan aa gba osi, bi wọn ṣe ma pin ara wọn kaakiri ree titi ti idibo aa fi pari, ti Yoruba ò si ni i ri nnkan gidi kan mu jade lati inu ibo naa. Bii ṣee ri fun Yoruba ree. O ti tun bẹrẹ bayii o, Ọlọrun ma jẹ ki Yoruba tun pada mofo. Ẹni ba n ka ọrọ yii, o le sare sọ pe ki i ṣe Yoruba nikan, bo ṣe maa n ri fun Hausa ati Ibo naa niyẹn, awọn naa n pin bi ibo ba n bọ. Ootọ ni, nitori ko si ẹya kan ti gbogbo wọn n sun ti wọn n kọri sibi kan. Iyatọ to wa ni ti Hausa ati Ibo ni pe ti wọn ba bara wọn ja lasiko ibo bẹẹ, bi ibo ba ti pari, wọn aa di ọrẹ pada, bi anfaani kan ba si yọ nibi ibo naa, wọn aa jọ maa jẹ ẹ ni.

Ti Yoruba ò ri bẹẹ. Ija tawọn aṣaaju wa n ba ara wọn ja ki i i tan, ìjaa titi aye ni. Lati igba tija awọn oloṣelu wa ti bẹrẹ laye Awolọwọ, titi dìsìnyí, wọn ki i dari ji ara wọn, wọn koriira ara wọn debii pe wọn le pa ara wọn ti wọn ba pade ninu ookun. Ikoriira buruku yii ni ki i jẹ ki wọn le fohun ṣọkan nibi ohunkohun. Aṣaaju ọtun aa ṣe tiẹ lọtọ, aṣaaju osi aa ṣe tiẹ lọtọ, nigbẹyin, awọn ti wọn ko gbọn to wọn, ṣugbọn ti wọn ni iṣọkan laarin ara wọn aa rá si wọn laarin, wọn aa si ko anfaani to yẹ ki Yoruba jẹ lọ. Nitori nigba tawọn agba yii ba n ba ara wọn ja ija ajadiju, ti wọn lawọn ko ni i bara awọn ṣe, ti wọn n tori ifẹ tara wọn nikan ti wọn n lodi sira wọn, ṣugbọn ti wọn aa ni Yoruba lawọn n ja fun, awọn ti wọn jẹ ọmọ Yoruba tootọ ko ni i mọ ibi ti wọn maa ya si, wọn aa kan maa rin pondoro-pondoro kiri bii agutan ti ko loluṣọ ni.

Yoruba ko si loluṣọ loootọ, nitori ko sẹni kan bayii to ku to n ronu fun Yoruba mọ. Ko si laarin ọba ko si laarin oloṣelu, nitori ati ọba atawọn oloṣelu yii, awọn n forukọ Yoruba jẹun lasan ni. Nibi ti wọn ti n ṣe eleyii ni wọn ti fa Yoruba sẹyin, nibi ti wọn si ba wa de bayii, Ọlọrun nikan lo mọ ibi ti Yoruba aa gbẹyin si. Mo wo ohun to n ṣẹle si Afẹnifẹre loni-in yii, ẹgbẹ ti wọn pe lẹgbẹ awọn agbaagba Yoruba, omi si fẹrẹ maa ja bọ loju mi. Idi ni pe iyi to wa lara Afẹnifere ti tan, awọn oṣelu ati awọn agba Yoruba ti wọn n ṣe atako ara wọn ti lu ẹgbẹ ọhun fọ. Ẹgbẹ to yẹ ko jẹ igi iṣọkan fun Yoruba, to yẹ ko jẹ ọpa ti Yoruba maa mu dani fi mọna, wọn ti lu ẹgbẹ naa fọ mọ ara wọn lori, wọn ba a jẹ pata. Nitori pe ẹgbẹ yii bajẹ ni Yoruba ṣe pin si yẹlẹyẹlẹ, tori awọn aṣaaju Afẹnifere yii ti pin tipẹ.

 

Nigba ti mo rohun to ṣẹlẹ ni Akurẹ, ti Bọla ko awọn Yoruba pataki pataki kan lẹyin, ti wọn lọ sile Baba Faṣọranti, ti wọn ni ọdọ Afẹnifẹre lawọn lọ, mo mi kanlẹ, mo ni ọrọ doju ẹ wayi!  Onijibiti, ọmọ buruku gbaa, ni Bọla! Gbogbo ẹnu ni mo si fi sọ bẹẹ. Jibiti ni Bọla lu Yoruba, jibiti lo lu awọn Afẹnifẹre. Oun naa mọ pe jibiti ni, awọn ti wọn tẹle e naa mọ pe jibiti ni. Jibiti ni, nitori Faṣọranti kọ lolori Afẹnifẹre. Gbogbo awọn ti wọn tẹle Bọla atawọn ti wọn duro de e lọdọ baba yii, ẹni kan ṣoṣo leeyan le sọ pe o ṣi wa ninu Afẹnifẹre, iyẹn ni Kọle. Awọn to ku ti kuro ninu ẹgbẹ yii tipẹ gan-an! Bẹẹ awọn Bọla yii ni wọn fọ Afẹnifẹre o, oun ati Bisi (Akande), ati Ṣẹgun (Ọṣọba). Wọn lu ẹgbẹ naa fọ pata. Ṣugbọn lasiko yii ti wọn nilo pe kawọn ara ilẹ Hausa mọ pe awọn Yoruba naa wa lẹyin Bọla, wọn gbe ọgbọn jibiti dide, wọn lọ sile Faṣoranti, wọn loun lolori Afẹnifẹre.

 Lẹyin tawọn Fulani ajinigbe ti pa Funkẹ, ọmọ  baba yii ni Ọrẹ, ni 2019, ibanuje ọjọ naa ko jẹ ki baba le ṣe akitiyan Afẹnifẹre mọ, o si kọwe fipo olori wọn silẹ nigba to ya, o lagbara oun ò gbe e mọ. Ninu ẹgbẹ wọn yii, bi aṣaaju kan ba kuro, igbakeji ẹ lo maa gbapo ẹ, iyẹn lo sọ Baba Adebanjọ di olori Afẹnifẹre. Amọ Bọla atawọn eeyan ẹ ko le lọ sile Adebanjọ, nitori Adebanjọ ti ni Obi lawọn Afẹnifẹre n ba lọ. Awọn Bọla ko ri ẹgbẹ mi-in ti wọn le lọọ sa ba tawọn Hausa maa gba pe ẹgbẹ Yoruba ni, Afẹnifẹre nikan ni wọn mọ. Iyẹn ni wọn ṣe ji Faṣọranti dide bii olori Afẹnifẹre. Bẹẹ Faṣọranti ti awọn Bọla lọọ ba yii, o le lọdun mẹwaa ti wọn fi ba a ja, oun, Bisi, Ṣegun, atawọn ẹgbẹ wọn to ku. Wọn binu jalẹ, wọn lawọn ko ni i gba pe Faṣọranti lolori Afẹnifẹre, wọn ni ẹni ti awọn mu ni tawọn ni Ayọ Fasanmi. Nitori pe Fasanmi ko si laye mọ bayii lawọn onijibiti oṣelu yii ṣe yi sọdo Faṣọranti.

 Ki lo de tawọn Bọla ko gba pe Faṣọranti ni aṣaaju Afẹnifẹre nigba ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ to ku ti yan an nijọsi, ti wọn si n ṣepade nile ẹ l’Akurẹ. Ṣebi nitori ija oṣelu yii naa ni, nitori pe awọn Bọla fẹ ko jẹ Bisi lo maa ṣe alaga ẹgbẹ AD, tawọn baba to ku ni Mojisoluwa Akinfẹnwa lawọn fẹ. Bọla ṣaaju awọn ẹgbẹ ẹ ti wọn jọ ṣe gomina pe ti Akinfẹnwa ba jẹ alaga AD, awọn ko ni i le lo o sibi ti awọn ba fẹ, ṣugbọn to ba jẹ Akande ni, bii bọọlu lawọn le gba a sibi to ba wu awọn. Ṣebi iyẹn ni wọn ṣe ko owo ati gbogbo agbara ti wọn ni fi tẹle Bisi lẹyin pe dandan ni ko ṣe alaga AD, ti wọn ni awọn maa ni Afẹnifẹre tawọn naa, ki Fasanmi ṣe alaga Afẹnifẹre awọn nitori  Oṣogbo lo n gbe, ajọṣe si wa laarin oun ati Bisi. Bẹẹ ni wọn fọ AD, ti wọn fọ Afẹnifẹre. Ohun ti wọn si ṣe koriira Faṣọranti, ti wọn o delẹ ẹ, niyẹn.

Igba ti ọmọ Faṣọranti yii ku ti gbogbo eeyan n sọ pe awọn Fulani lo pa a, awon Afẹnifẹre ayederu yii lọ sibẹ. Ṣugbọn ki i ṣe pe wọn lọọ ba Faṣọranti daro, wọn lọ lati ta ko awọn to n sọ pe Fulani lo pa ọmọ ẹ ni. Bọla ni awọn to n sọ pe Fulani lo pa Funkẹ, nibo ni maaluu awọn Fulani naa wa, tori nibi ti ko ba ti si maaluu, Fulani ki i si nibẹ, ki i ṣe Fulani lo pa ọmọ Faṣọranti. Igba ti wọn mu awọn ọdaran naa, ti wọn ri i pe loootọ Fulani ni wọn, Bọla ko pada wi kinni kan mọ. Ohun to n tori ẹ sọ bẹẹ nigba naa ni pe ko fẹ kawọn Buhari binu, ki wọn le gbejọba foun. Wọn ni Afẹnifẹre ko daa, sibẹ wọn ko ri ẹgbẹ mi-in fi rọpo ẹ. Kaka ki wọn si jokoo ki wọn ba ara wọn sọrọ, ki wọn tun ẹgbẹ naa ṣe, jibiti bayii ni wọn maa n lu araalu bi oṣelu ba ti de, ti awọn kan aa ko ara wọn lẹyin tẹle Bọla, ti wọn aa ni awọn l’Afẹnifẹre, bẹẹ irọ buruku ni.

Eeyan ko si le bu Bọla atawọn ti wọn n tẹle e yii o, awọn aṣaaju Afẹnifẹre funra wọn lo ti da nnkan wọn ru lati ibẹrẹ. Ṣebi awọn ọlọgbọn kilọ fun wọn to, pe ti wọn ba fẹẹ ṣe e daadaa, ki wọn ri i pe Afẹnifẹre ko da sọrọ oṣelu, ọrọ Yoruba nikan ni ki wọn maa da si, pe ki ẹgbẹ naa jẹ ẹgbẹ awọn aṣaaju Yoruba nikan. Ṣugbọn awọn ti wọn fẹran oṣelu ninu wọn o gba, wọn fẹẹ jẹ aṣaaju Yoruba, ki wọn tun jẹ aṣaaju oloṣelu, wọn n fi ara wọn we aye Awolọwọ, bi wọn ṣe lu kinni naa fọ mọ ara wọn lori niyẹn. Ṣugbọn akoba lo ṣe fun Yoruba. Loni-in, Yoruba o le duro ki wọn lẹni kan laṣaaju awọn! Bi a ti n sọro yii, olukọ agba kan ni Yunifasiti Ibadan, igbakeji olori yunifasiti naa nigba kan, Adigun Agbaje, awọn Fuani ji i gbe ni gbangbaa titi marosẹ Ibadan. Asiko tawọn olukọ ẹgbẹ ẹ n da owo tawọn Fulani lawọn fẹẹ gba jọ lawọn Bọla wa lọdọ Faṣọranti ti wọn n ṣe yalayolo yii, ko sẹni to ranti aburu to n ba Yoruba lọwọlọwọ ninu wọn.

Yoruba ko lolori, nnkan wa ko si daa. Awọn ọmọ wa ko ni adari to le fọna han wọn, awọn aṣaaju wa ti gbabọde. Radarada ni pupọ ninu wọn n ba kiri, awọn agbalagba to yẹ ka ba nidii ọgbọn, idi agọ la ba wọn, ti wọn n fi agbalagba ara jo langba-langba kiri. Ṣe awọn baba nla wa ṣe aṣiṣe ni, abi bawo ni gbogbo ẹ kuku ṣe daru bayii fun Yoruba!

 

 

Leave a Reply