Ṣe ẹyin naa ri i nigba ti Tinubu pade Atiku lọjọsi

ỌMỌỌDỌ AGBA

Lọsẹ to kọja yii, awọn oludije fun ẹgbẹ oṣelu nla mejeeji ta a ni nilẹ yii pade ara wọn. Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu pade Alaaji Atiku Abubakar, ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, niluu Abuja ni wọn ti pade ara wọn. Kaluku n ba irinajo rẹ lo ni wọn fi pade, ṣugbọn ohun to ṣe koko ni bi wọn ti kan ara wọn kuu nibi ijokoo awọn ọlọla to ba fẹẹ wọ ẹronpileeni, niṣe ni wọn dide, ti wọn bẹrẹ si i pariwo orukọ ara wọn. Bi Tinubu ti n pariwo Atiku, bẹẹ ni Atiku n pariwo Aṣiwaju, bẹẹ ni awọn eeyan ti wọn tẹle wọn naa si n da si i, ti wọn di mọ ara wọn. Ọrọ naa ko to ohun to yẹ ko gba gbogbo oju iwe iroyin ati ori ẹrọ ayelujara kan, ṣugbọn nitori bi nnkan tiwa ṣe ri ni Naijiria yii lọrọ naa ṣe di ariwo. Idi ariwo naa si ni pe loju awọn to n tẹle Tinubu, bii ki wọn ri Atiku, tabi ẹnikẹni to ba ni oun n ṣe ti Atiku, ki wọn ya a si wẹwẹ ni, wọn ko si lero rara pe ti Tinubu ba pade Atiku yii nibikankan ti yoo ki i. Bakan naa lo ri loju awọn to n tẹle Atiku o, awọn naa ko ni ifarada rara, loju wọn, bii ki wọn ri Tinubu tabi awọn ti wọn n tẹle e ki wọn ju wọn loko pa bii ọmọ eṣu lo ri, awọn naa ko si lero pe bi Atiku ba pade Tinubu, ko ni i gbegbaaju fun un. Ṣugbọn bi ọrọ oṣelu ba ri bẹẹ ni orile-ede mi-in, ko ri bẹẹ ni Naijiria yii rara o, nitori kinni kan wa to pa awọn oloṣelu tiwa pọ, apapin lo n jẹ. Awọn oloṣelu ilẹ yii mọ pe ẹnikẹni to ba wa nipo ninu awọn ni ikoko ọbẹ wa lọdọ rẹ, kia ni gbogbo wọn yoo si ti sun mọ ọn, ti wọn yoo maa la a. Wọn ki i ba ara wọn ṣe ọta debi apapin, ikoko ọbẹ ni wọn n du mọ ara wọn lọwọ ti ẹ n ri yii, ẹni ba si ti ja mọ lọwọ, kia lawọn to ku yoo sun mọ ọn pe ọmọọya, jẹ ka jọ maa la a. Ohun to fa a ti awọn oloṣelu yii ki i fi i nitiju lati kuro ninu ẹgbẹ kan ti wọn ti wa tẹlẹ ki wọn tun sa lọ sinu ẹgbẹ mi-in niyẹn. Wọn le paara ẹgbẹ kan lẹẹmeji, wọn yoo jade, wọn yoo tun pada wọle, to ba si tun wu wọn, wọn yoo tun sare jade, ẹni ba wo irinajo Atiku funra rẹ yoo mọ bi ọrọ awọn oloṣelu yii ṣe ri. Bi eeyan ko si mọ iru Atiku, ko wo ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni Fani Kayọde, ẹni to jẹ to ba bu iya wọn ninu ẹgbẹ yii lonii to fi baba wọn le e, nitori pe o n lọ sinu ẹgbẹ keji ni, to ba si ti denu ẹgbẹ to n lọ ni yoo ki epe mọlẹ, ti yoo maa ṣẹ ẹ fun awọn to ṣẹṣẹ kuro lọdọ ẹ, nibi to ti n jẹ to ti n mu fun ọpọlọpọ ọdun. Eleyii ko ni ko ma tun sa kuro ninu iyẹn naa lọjọ kan, ti ounjẹ to n jẹ nibẹ ba ti tan, yoo dẹyin, ọọkan ibi ti ounjẹ ba tun wa ni yoo lọ, koda ko jẹ ibi to ti kuro to ti bu wọn naa ni, yoo pada sibẹ, yoo si tun maa bu awọn to ti jẹun bii ọjọ meloo kan lọdọ tiwọn. Bawọn oloṣelu wa ṣe ri ni Naijiria ree, nibi ti ọbẹ ba ti dun ni wọn n lọ. Wọn ko tori araalu ṣoṣelu aṣelaagun, adaba wọn ko wa ounjẹ si ọfun orofo, nitori ounjẹ kaluku lo ṣe n ṣoṣelu aṣekara. Ṣugbọn awọn araalu ko mọ eleyii, ọrọ ti ko kan wọn rara, ohun ti wọn o mọdi ati bo ṣe jẹ bẹẹ ni wọn yoo maa tori ẹ gbe ẹwu silẹ, ti wọn yoo maa gbe apẹre wọ, oloṣelu ti wọn ba n ri kinni kan jẹ lọdọ ẹ, tabi ti wọn ro pe awọn le ri kinni kan jẹ lọdọ ẹ, tabi ti wọn kan n gbọ orukọ ẹ lasan ti wọn ko mọ, oun ni wọn yoo maa tori ẹ ja, ti wọn si le ba ọmọọya wọn, ọrẹ wọn, iyawo wọn ja nitori pe ko tẹle oloṣelu jẹgudujẹra ti awọn fẹran. Ohun to maa n da wahala silẹ ree, ti awọn oloṣelu fi maa n ri araalu lo, ti awọn ọmọ kan yoo maa paayan lorukọ oloṣelu, ti awọn kan yoo maa ba dukia ati iṣẹ ẹlomi-in jẹ nitori oloṣelu kan. Bẹẹ awọn oloṣelu yii ki i ṣe bẹẹ laarin ara wọn, nitori ọrẹ ti wọn ti n ba ara wọn ṣe bọ, ọjọ ẹ pẹ. Ṣe Atiku ni yoo ba Tinubu ja! Tabi Tinubu ni yoo ba Atiku ja, lawọn ti wọn ti jọ n ṣe bọ lati bii ogoji ọdun. Ṣugbọn awọn ti wọn n tẹle wọn ko mọ, ọta ti yoo dina ounjẹ wọn, tabi ti yoo ba ọjọ ọla wọn jẹ ni wọn maa n ba ara wọn ṣe. Atiku lo pade Tinubu ti ko sija yii, o dijọ tọmọ APC ba pade ọmọ PDP ki wọn too yọ ada yọ ọbẹ sira wọn. A ko fẹ iru iyẹn lasiko ibo to n bọ yii o, ti Ọlọrun ba fi ni ka dibo naa, ki kaluku ti ọwọ ọmọ ẹ bọ aṣọ. Ki ọlọmọ kilọ fọmọ ẹ paapaa, oloṣelu kan ko too tori ẹ ku, ẹni to ba tori oloṣelu Naijiria ku, o kan ku iku ẹsin lasan, ọrun apaadi lo n lọ!

 

Leave a Reply