Ṣeyi Makinde maa lọ lọdun 2023, awa la maa ṣejọba naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ – Adelabu

Ọlawale Ajao, Ibadan
Ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress (APC), ipinlẹ Ọyọ ti n ṣeto labẹnu lati fa ọkan ninu awọn to n dije dupo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn kalẹ nibi idibo abẹlẹ ẹgbẹ ọhun ti yoo waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Agba oṣelu ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Ayọ Ademọla Adeṣeun, lo sọ eyi di mimọ nibi eto ikede ti Oloye Abdul Waheed Adebayọ Adelabu ti sọ fun gbogbo aye pe oun ti ṣetan lati tun dupo gomina ipinlẹ naa.
Nile-ẹgbẹ oṣelu APC to wa laduugbo Oke-Ado, n’Ibadan, leto ọhun ti waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.
Adeṣeun, ẹni to ti figba kan ṣoju ẹkun idibo Aarin Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja, sọ pe loju awọn eeyan lo ti da bii ẹni pe ko si iṣọkan ninu ẹgbẹ APC ipinlẹ yii, ṣugbọn ko ri bẹẹ, koda, oun fi da gbogbo aye loju pe oju kan naa ni gbogbo awọn oludibo ẹgbẹ n lọ lọjọ idibo abẹlẹ lati yan oludije sipo gomina lorukọ ẹgbẹ naa, nitori awọn agba ẹgbẹ ọhun ti fẹnu ko lati panu pọ fa ọkan ninu awọn to n dupo naa kalẹ gẹgẹ bii oludije wọn.
O ni “ọla (Jimọ ọsẹ to kọja) lo yẹ ka dibo abẹle wa tẹlẹ, ẹgbẹ ti sun un si ọjọ mẹjọ oni. Ko ni i si pe a n ja nibẹ. Gbogbo ẹni to yẹ ka ba sọrọ, a ti ba wọn sọrọ, gbogbo wọn ti gbọ. Ọjọ mẹjọ oni (Tọsidee) ọsẹ yii, la maa nawọ Bayọ Adelabu soke gẹgẹ bii ẹni to maa dupo gomina lorukọ ẹgbẹ wa”.
Nigba to n sọ awọn ipinnu to ni fawọn araalu bo ba papa depo gomina lọdun to n bọ, Oloye Adelabu, tawọn eeyan tun mọ si Pẹnkẹlẹmẹẹsi tọka si eto aabo, eto ilera ati eto ẹkọ gẹgẹ bii awọn nnkan ti oun yoo mu lọkun-un-kundun ninu ijọba rẹ, paapaa nitori ti gomina to wa lori aleefa lọwọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde kuna lori awọn nnkan wọnyi.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ẹni to pera ẹ ni gomina ilu, awọn to ko lẹyin, wọn n pa awọn ọlọpaa, wọn si tun n sun ẹran wọn jẹ. Ṣo yẹ ki ijọba maa ṣe bẹẹ. Gbogbo ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn dana sun latigba naa, wọn o ti i ri nnkan kan ṣe si i di baa ṣe n sọrọ yii. A fẹẹ tun gbogbo ẹ kọ pada, wọn (ijọba) ni ka ma ṣe e. Garaaji ni wọn n fowo kọ kiri, wọn tun ni ki wọn maa muti nibẹ, awọn awakọ aa waa muti, wọn aa wa awọn ero pa.

“Inu awọn tiṣa ko dun, wọn waa lawọn n san salari, bẹẹ, wọn o fun wọn lowo to yẹ ki wọn maa fi ra awọn nnkan ti wọn nilo lati fi kọ awọn ọmọ. Lagbara Ọlọrun, ayipada maa de ba gbogbo nnkan wọnyi, gbogbo ileewe lawa maa tun ṣe.
“Gbogbo ileewosan lo ti dẹnu kọlẹ. Ki waa niṣẹ ijọba, wọn o le ṣeto ilera, wọn o le ṣeto aabo ati eto ẹkọ, ki waa niṣẹ wọn gan-an? Seyi maa lọ lọdun 2023, awa la si maa ṣe jọba naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.”
Diẹ ninu awọn agba oṣelu to wa nibi eto ọhun ni Amofin Sarafadeen Alli, ẹni to tun ṣoju Sẹnetọ (Agba-Oye) Rashidi Ladọja ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri; igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Ọtunba Moses Alake; Abu Gbadamọsi (alaga igun keji ẹgbẹ APC Ọyọ); Oloye Akinade Fijabi; Wasiu Ajimọbi (aburo gomina ana); Alhaji Isiaka Alimi (igbakeji alaga APC Ọyọ tẹlẹ) ati Ọnarebu Asimiyu Alarape ti i ṣe abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri.

Leave a Reply