Aderounmu Kazeem
Ọkunrin sọja kan ti won ko darukọ ẹ la gbọ pe o fa ibọn ẹ yọ laipẹ yii, ki ẹnikẹni si too sunmọ ọn, niṣe lo yin in lura ẹ lori, lo ba ku patapata. Lara awọn t iwon koju awonm ọ̄o ogun afẹmiṣofo ni.
Awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn sọ pe ko too di pe ọkunrin yii gbẹmi ara ẹ lo ti kọ iwe pelebe kan silẹ, ninu ẹ naa lo ti ṣalaye ohun to fa sababi to fi da ẹmi ara ẹ legbodo.
Abẹ ẹka ileeṣẹ oloogun orilẹ-ede yii, eyi ti wọn pe ni Army’s 27 force Brigade ni Buni Gari nipinlẹ Yobe lọhun-un niṣẹlẹ buruku ọhun ti waye. Ọkan lara awọn ṣoja ilẹ yii to n gbogun ti awọn janduku Boko Haram gan-an ni wọn pe ọkunrin kọburu ninu iṣẹ oloogun yii.