Ṣọọṣi l’Ọpẹyẹmi atiya ẹ n lọ tawọn ajinigbe fi ja a gba mọ ọn lọwọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọlọrun ti ọmọbinrin ọmọọdun mẹsan-an kan to n jẹ Afọlabi Ọpẹyẹmi n sin, lo ko o yọ lọwọ fitina pẹlu bo ṣe ko sọwọ awọn ajinigbe laduugbo Alakia-Adelubi, n’Ibadan, nigba to n lọ si ṣọọṣi lọọ jọsin f’Ọlọrun rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Ọlọrun yii kan naa lo gba awọn afurasi ajinigbe meji ọhun, Kabiru Salami ati Lukman Adisa, la lọwọ iku oro pẹlu bi aṣiri wọn ṣe tu, tawọn araadugbo ọhun si pinnu lati lu wọn pa, ki wọn si dana sun oku wọn lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa yara yọ sibẹ lati doola ẹmi wọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Ọpẹyẹmi atiya ẹ ni wọn jọ n lọ si ṣọọṣi ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju laaarọ ọjọ Aiku, Sannde ọhun, ṣugbọn eyi ko to lati le awọn ẹruuku jinna ṣọmọ naa, niṣe lawọn ogboju ajinigbe ọhun ja ọmọ yii gba lọwọ iya ẹ bii igba ti aṣa ba gbe oromọdiẹ lẹyin iya ẹ.

Ariwo ti iya ọmọ naa, Modupẹ Afọlabi, pa lawọn araadugbo gbọ ti wọn fi tu jade, ti wọn fi le Kabiru ati Lukman mu nibi ti wọn ti n sa lọ.

Lẹyin ti awọn araadugbo ti fẹẹ fi lulu gbẹmi awọn afurasi ọdaran yii ni wọn ṣeto lati dana sun wọn, ki ohun to n run kuku tan nilẹ pata. Nigba naa lawọn ọlọpaa yọ lojiji, ti wọn si doola ẹmi awọn ọbayejẹ eeyan naa.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, ni Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe awọn to wa nitosi agbegbe Alakia-Adelubi, ninu awọn ọlọpaa to n mojuto eto aabo kaakiri  ipinlẹ Ọyọ, lo doola ẹmi awọn afurasi ọdaran naa.

 

Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, ti paṣẹ fawọn ọlọpaa lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa kiakia lati le fiya to ba tọ jẹ awọn afurasi ọdaran naa gẹgẹ bi SP Ọṣifẹṣọ ṣe fidi ẹ mulẹ siwaju.

Leave a Reply