Ṣọọbu ni Mariam wa to ti n taja ti ibọn awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fi lọọ pa a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

K’Ọlọrun ma jẹ ki abiamọ foju sunkun ọmọ. Nibi ija agba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni ibọn ti ba ọmọ iya meji, Mariam, ẹni ọdun mẹwaa, ati aburu rẹ, Abdulraheem, ọmọ ọdun mẹta, lagbegbe Ọja Ọba, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara. Mariam ku loju-ẹsẹ, Abduraheem to jẹ aburo rẹ si farapa yanna yanna.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ko kọja, ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fija pẹẹta, wọn bẹrẹ si i yinbọn soke lera lera, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi wọn. Ṣọọbu Kẹhinde ti i ṣe iya awọn ọmọ ọhun to n ta burẹdi ni awọn ọmọ iya meji naa wa ti ibọn ti lọọ ba wọn

ALAROYE gbọ pe ẹgbẹ Ẹyẹ ati Aiye ni wọn ni wọn gbena woju ara wọn, ti wọn rẹ ara wọn danu bii ila niluu Ilọrin ati gbogbo agbegbe rẹ, ti wọn si ti n jija agba naa lọjọ to pẹ. Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ torukọ rẹ n jẹ Ẹfọ to jokoo si ile fiimu to sunmọ Ọja ọba ni awọn ọmọ ẹgbẹ Aiye fẹẹ yinbọn pa ti wọn fi n yinbọn leralera, to fi lọọ ba awọn ọmọ iya meji ọhun ni ṣọọbu iya wọn, Mariam ku, aburo rẹ, Abdulraheem, si n gba itọju nileewosan.

Lara awọn oniṣowo to n taja lọja naa ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ, Iyabo Uthman, to ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, sọ pe ṣe ni darudapọ waye lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa bẹrẹ si i yinbọn ninu ọja, ti onikaluku si n sa alasa fun ẹmi ara wọn, o tẹsiwaju pe ọpọ ontaja ni ko le wa si ṣọọbu rẹ ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, latari ibẹru bojo.

 

Leave a Reply