Ṣoyinka fọwọ si ẹṣọ Amọtẹkun, o ni Fulani darandaran, Boko Haram lo n dari Naijiria 

Dada Ajikanje

Bi wahala ijingbe, iṣẹmilofo atawọn iwa ọdaran mi-in ṣe n gbilẹ si i lojoojumọ, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti sọ pe o ṣe pataki ki idasilẹ ẹṣọ Amọtẹkun tubọ wa daadaa lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria.

Bo ṣe gboriyin fun awọn ọdọ nipa bi wọn ṣe jade ta ko wahala tawọn ẹṣọ agbofinro SARS n ko ba ilu, bẹẹ lo sọ pe idasilẹ awọn ẹṣọ Amọtẹkun to ti wa lawọn ipinlẹ kan nilẹ Yoruba yẹ ko wa lawọn ipinlẹ kan si i.

Ṣa o, Ọjọgbọn yii ti sọ pe ko ni i daa rara ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun naa ba pada waa sọ ara wọn di ẹṣọ agbofinro SARS mi-in lẹyin ti wọn ba ti fidi mulẹ daadaa tan.

Lori eto kan to ṣe lori amohunmaworan ‘Arise TV’ lo ti sọrọ yii. Bakan naa lo sọ pe eto iwọde tawọn ọdọ Naijiria ṣe lati fi ta ko awọn ẹṣọ agbofinro yii fi han pe wọn mọ ohun ti wọn n ṣe, nitori ọna ti wọn gbe e gba ati bi wọn ti ṣe e.

Ṣoyinka sọ pe, “O pẹ ti a ti n woye pe o yẹ ki awọn ọdọ yii ti dide lati ja fun ọjọ ọla wọn. Bakan naa ni ibeere n waye pe njẹ awọn ọdọ yii mọ pe niṣe ni nnkan n buru si i lorilẹ-ede yii, ati pe njẹ wọn mọ pe awọn gan-an ni wọn n pada bọ waa jogun wahala ati idaamu yii to ba ya?

“Nigbẹyin, awọn ọdọ yii dide, bẹẹ lo jẹ ohun iwuri fun pupọ ninu wa pe wọn ti dide lati ni ọjọ ọla to dara.”

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti ke si awọn ipinlẹ ti wọn ko ti i da ẹṣọ Amọtẹkun silẹ lati ṣe bẹẹ. O lohun to foju han bayii ni pe eto iṣakoso orilẹ-ede yii wa lọwọ awọn Hausa darandaran, awọn Boko Haram, ati awọn kan ti wọn pe ni ISWAP, bẹẹ lawọn eeyan yii ko ni igbagbọ kankan ninu iṣokan orilẹ-ede yii.

Leave a Reply