Ṣoyinka tun kọ lu Buhari, o ni ijọba rẹ ko lokun lati gbogun ti iwa ibajẹ mọ

Faith Adebọla, Eko

“Ti ki i baa ṣe pe o ti rẹ ijọba yii, ti wọn o lokun ninu mọ ni, ọpọ eeyan to yẹ ko wa lẹwọn bayii ni wọn n yan kiri igboro, tori gbogbo nnkan o lọ bo ṣe yẹ ko lọ mọ. Ọpọ ẹjọ lo wa ni kootu tawọn ẹlẹrii ti taṣiiri bawọn gomina kan ṣe n ji owo pamọ diẹ diẹ kawọn agbofinro ma baa fura si wọn. Aṣiri ti waa tu, afẹfẹ ti fẹ, a ti ri furọ adiyẹ. Ṣugbọn lojiji, ariwo ẹjọ naa yoo kan ṣe ‘wẹlo’ ni, lẹnikan o ba ni i gbọ nnkan kan mọ. Ajọ EFCC ti mo maa n fi yangan, ti mo si ti lẹyin nigba aye Nuhu Ribadu, lo di pe wọn o mọ ohun ti wọn le ṣe mọ.”

Ogbontarigi ọmọwe ati ọnkọwe nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, lo sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, lati fi aidunnu rẹ si bi iwa ibajẹ, ikowojẹ, ajẹbanu atawọn iwa aitọ mi-in ṣe n peleke si i lasiko yii lorileede wa.

Lori eto tẹlifiṣan ileeṣẹ AIT kan ni Ṣoyinka ti n dahun awọn ibeere tawọn oniroyin bi i, o ni iṣakoso yii ti sọ EFCC atawọn ajọ tawọn jẹgudujẹra n bẹru nigba kan di ẹṣin inu iwe, o ni niṣe ni aja EFCC kan n gbo bayii, ko le ṣọdẹ rara.

O ni ailonka ẹjọ ti EFCC ni awọn n ṣe ta ko ẹni to kowo jẹ lo jẹ pe ariwo ibẹrẹ nikan lawọn eeyan n gbọ, ko sẹni to tun maa gbọ nnkan kan mọ leyin ariwo akọkọ, ati pe ti wọn ba tiẹ lawọn gba idajọ fun afurasi ọdaran kan, ko ni i pẹ ti idajọ naa yoo fi di wiwọgi le latari awọn ọna ti ko muna doko ti ajọ ọhun fi n ko ẹri rẹ jọ.

Ọjọgbọn naa fikun un pe bawọn aṣofin ṣe n fẹ lati wa ni ipo alaga awọn igbimọ alabẹṣekele, nibi ti wọn ti le ri ọwọ pọn la daadaa ti sọ awọn aṣofin paapaa di gbẹwu-dani fun ileeṣẹ alaṣẹ.

O lo yẹ kawọn eeyan tawọn aṣofin naa n ṣoju fun le maa ran wọn leti ojuṣe wọn nigba ti wọn ba ti n kẹrẹ nidii iṣẹ aṣoju wọn, ki wọn si pawọ-pọ fi ibo yọ wọn danu ti ko ba si ayipada rere kan latọdọ wọn.

O ni nibi tawọn araalu ba ti mọyi agbara ti wọn ni lati pe awọn adari wọn sakiyesi, ko yẹ ki nnkan mẹhẹ to bo ti ri lorileede yii rara.

Leave a Reply