Ọlọpaa mẹta dero ahamọ l’Owode-Ẹgba, owo ti wọn fipa gba lọwọ akẹkọọ LASU lo ko ba wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Fun pe wọn fi ipa gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ  ati mẹta naira, (153,000) lọwọ akẹkọọ ileewe LASU kan torukọ ẹ n jẹ Sheriff Adedigba, awọn ọlọpaa mẹta yii, Inspẹkitọ Sunday Johh, Sajẹnti Jimọh Asimiya ati Sajẹnti Solomon Adedapọ ti wa lahaamọ l’Owode-Ẹgba, nipinlẹ Ogun.

Ọga ọlọpaa pata nipinlẹ yii, CP Edward Ajogun, lo paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọlọpaa mẹta naa da si atimọle, lẹyin ti aṣiri owo ti wọn gba lọwọ akẹkọọ naa tu lori ayelujara.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ latẹnu DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, o ni akẹkọọ Yunifasiti LASU naa n pada s’Ekoo ni, lati Abẹokuta.

Nigba to de Owode-Ẹgba ni awọn ọlọpaa mẹta naa da a duro, ti wọn si fi jijẹ ọlọpaa wọn gba owo ọwọ rẹ lọna aitọ.

Nigba ti aye si ti di ti Fesibuuku,Tuita atawọn mi-in to wa lori ayelujara, ko pẹ ti akẹkọọ ti wọn gbowo lọwọ ẹ fi sọ ohun to ṣẹlẹ sori afẹfẹ, n lo ba n tan kaakiri. Eyi ni CP Edward Ajogun ri, to fi paṣẹ fun DPO Owode-Ẹgba, pe ko wa awọn abanilojujẹ ọlọpaa mẹta naa jade kia.

Bẹẹ ni ọlọpaa mu awọn ọlọpaa ti wọn fipa gbowo yii, wọn ko wọn lọ si atimọle lẹka ti wọn ti n fiya jẹ agbofinro to ba kọja aala, ibẹ naa ni wọn yoo si wa titi ti wọn yoo fi da sẹria to tọ si wọn gẹgẹ bi Alukoro ṣe sọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun rọ awọn araalu pe ki wọn ma jẹ ko pẹ rara ti wọn yoo fi fẹjọ ọlọpaa to ba huwa to lodi sofin sun, ki wọn tete waa sọ nibi ti wọn yoo ti fiya to tọ jẹ ẹ ni.

Bakan naa lo kilọ fawọn agbofinro pe ki wọn yee gbe ofin ṣanlẹ, o ni ki wọn ma huwa ti yoo ko abuku ba iṣẹ ọlọpaa, nitori aaye ko si fun palapala bẹẹ rara ni.

Leave a Reply