Ọlọpaa ko le da wa duro, dandan ni ka ṣewọde fun iṣọkan Yoruba l’Ọṣun ni Satide – Ọba Ogboni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluaye Ọba Ogboni agbaye, Ọba Adetoyeṣe Abdul Ọlakisan, ti kilọ fawọn agbofinro ti wọn ba n gbero lati da iwọde iṣọkan ilẹ Yoruba to fẹẹ waye niluu Oṣogbo ni ọjọ Abamẹta, Satide, duro lati tun ero wọn pa nitori awọn ko ni i ṣe ohunkohun to lodi si ofin orileede yii.

Ninu atẹjade kan ti kabiesi naa fi ṣọwọ si ALAROYE lo ti sọ pe aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ni iwọde naa, eleyii ti ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa United ati Ilana Ọmọ Ooduduwa ṣagbekalẹ rẹ, yoo waye.

Ọba Ọlakisan ṣalaye pe eredi iwọde alaafia naa ni lati ji awọn ọmọ Yoruba loju oorun wọn, ki wọn le mọ pe iṣọkan ti pada sinu iran naa.

O ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn yoo wọ aṣọ ẹgbẹjọda, bẹẹ si ni awọn ọmọ Yoruba atawọn ẹya mi-in ti wọn nifẹẹ lati darapọ le wa sibi eto naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “A ti ṣeto aabo to nipọn silẹ fun gbogbo awọn to maa wa nibẹ. Ẹni to bọwọ fun ofin ni wa, a ko si le ṣe ohunkohun ti yoo ta ko ofin orileede yii, idi niyẹn ti a fi n sọ pe ki awọn agbofinro ma wulẹ dabaa lati da wa duro.

“A ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo awọn agbofinro ki wọn le pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu ṣaaju, lasiko ati lẹyin iwọde naa.

“A n kilọ fun awọn janduku atawọn tọọgi ti wọn le fẹẹ darapọ mọ wa lati da wahala silẹ lasiko iwọde naa lati ma ṣe wa rara, nitori a ko ni i beṣu-bẹgba lati fa wọn le awọn agbofinro lọwọ.

“A ko wa lati gboju agan si ẹnikẹni tabi ba nnkan jẹ, bi ko ṣe lati la awọn eeyan wa lọyẹ lori idi ti wọn fi nilo lati fọwọsowọpọ pẹlu wa ki iran Yoruba le ni ominira patapata”

Leave a Reply