Sunday Igboho balẹ siluu Akurẹ, o ni dandan ni Orileede Oodua

Faith Adebọla

 Rẹgi lorin to gba ẹnu awọn ero rẹpẹtẹ ti wọn n wọ tẹle gbajugbaja ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ ti wọn n tun n pe ni Sunday Igboho, ṣe pẹlu bi awọn ọdọ atawọn agbalagba ṣe jade lọpọ nilu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Sátidé yii, ti wọn kede pe idasilẹ Orileede Oduduwa lawọn n fẹ, awọn si ti ṣetan lati ya kuro lara orileede Naijiria.

Orin ti wọn n kọ lakọgba fun Sunday Igboho ni pe ‘ko wo ẹyin rẹ wo, boya o lọmọ ogun tabi ko lọmọ ogun, ko wo ẹyin rẹ wo” lati ṣe koriya fun ọkunrin naa pe awọn wa lẹyin rẹ gẹgẹ bii ọmọ ogun nidii erongba idasilẹ Orileede Oduduwa ọhun.

Lati nnkan bii aago mẹsan-an owurọ la gbọ pe awọn ero ti n kora jọ fun iwọde ọhun, nnkan bii aago mọkanla si ni Sunday Igboho ti wọn n reti de saarin wọn.

Wọn ni bọkunrin naa ṣe de lawọn eeyan pariwo ẹ, ti wọn si n kede pe ‘Yoruba Nation la fẹ, Yoruba Nation lawa n ṣe, Orileede Oduduwa lawa n fẹ’.

Lẹyin ti Igboho ti ba awọn eeyan naa sọrọ tan, Imaamu Agba ilu Akurẹ, Oloye Aduranigba naa sọrọ, o si ṣadura fun Sunday Igboho pe Ọlọrun yoo ti i lẹyin lati ṣaṣeyọri.

Lati ikorita yii ni Sunday Igboho ti kọja saafin Deji tilu Akurẹ, Ọba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi, nibi toun atawọn ọba alaye mi-in ti wa nikalẹ lati gba Sunday Igboho lalejo.

Nigba ti Sunday Igboho dewaju awọn ọba alaye, o ṣalaye pe idi toun fi fa ara oun kalẹ lati ja fun idasilẹ Orileede Oduduwa ni lati gba ilẹ Yoruba lọwọ irẹnijẹ ati aisi ijọba rere ni Naijiria, paapaa latari bi awọn Fulani darandaran to n gbe ibọn rin ṣe n da ẹmi awọn eeyan legbodo nilẹ Yoruba.

O ni “Awọn oloṣelu ilẹ Yoruba kan ti ta wa fawọn Fulani tipẹ. Awọn naa ti ta wa fawọn Fulani tan, agbara wọn ko gbe e mọ lati gba wa silẹ. Fulani waa wọle si wa lara debii pe wọn n pa wa, a o le sọrọ, wọn n fipa ba awọn obinrin wa sun, a o le gbin, wọn n ji wa gbe, wọn aa ni ka lọọ gbe owo wa, ko si ohun ta a fẹẹ ṣe. Ti a ba tiẹ mu ninu wọn de agọ ọlọpaa, awọn ọlọpaa aa fi wọn silẹ ni, wọn aa sọ pe aṣẹ ti wa latoke pe kawọn fi wọn silẹ. O buru debii pe wọn tun n ṣe fidio ijinigbe wọn.

Baba wa Awolọwọ si ti sọrọ kan pe nigba to ba ya, awọn ọdọ lo maa ja ijangbara yii funra wọn. Asiko naa lo de yii, tori a ti ri i pe ọpọ awọn gomina wa atawọn baba wa ko le jade si gbangba sọrọ, nitori ipo oṣelu. Ṣugbọn awa ti mura tan, Ọlọrun si wa lẹyin wa.”

Awọn ọba naa si ṣadura fun un lẹyin ọrọ rẹ.

Leave a Reply