Irọ ni! Mowe, Ọfada ati Owode-Ẹgba ki i ṣe ibuba awọn ajinigbe- Alukoro ọlọpaa Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latari iroyin kan to n lọ lori ẹrọ ayelujura pe awọn agbegbe bii Mowe, Ọfada ati Owode-Ẹgba ko ṣee gba mọ, nitori ibuba awọn ajinigbe ni. Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ, o ni awọn ọna yii ṣee gba, wọn ko lewu rara, nitori wọn ki i ṣe ibuba awọn ajinigbe kankan.

Atẹjade ti Alukoro fi sita lori iroyin naa lo ṣalaye pe awọn to n gbe iru iroyin irọ bẹẹ jade kan fẹẹ da ipaya sọkan awọn eeyan lai nidii ni, paapaaa sọkan awọn olugbe ibẹ.

Oyeyẹmi sọ pe iṣẹlẹ ijinigbe kan ṣoṣo to waye lagbegbe naa ri ko ju ti obinrin kan tawọn ajinigbe ji gbe pẹlu alejo ẹ to wa a wa lati ilu Eko. O ni ninu oko kan ni wọn ti ji wọn gbe lọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un, awọn mejeeji ni wọn si ti gba itusilẹ, ti wọn ti pada sọdọ awọn eeyan wọn. Koda, o lawọn ti mu awọn afurasi kan latari awọn meji ti wọn ji gbe naa, awọn ti wọn si sa lọ paapaa ko le mori bọ, nitori ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n dọdẹ wọn.

O ni ijọniloju lo jẹ pe ẹnikan yoo kan jokoo ni kọrọ yara rẹ, yoo si maa ju ohun ti ko ṣẹlẹ sori ayelujara lati da wahala silẹ, nitori iṣẹlẹ ẹyọ kan ṣoṣo to ṣẹlẹ lọtọ.

“Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi asiko yii rọ gbogbo eeyan pe ki wọn ma gba iroyin ofege naa gbọ rara, nitori iṣẹ ọwọ awọn asorun-iwaju-pọ-mọ-tipakọ ni. Ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe ohun gbogbo lati ri i pe aabo wa faraalu, a si nilo ifọwosowọpọ gbogbo eeyan fun eyi.’’

Bẹẹ ni atẹjade ti Oyeyẹmi buwọ lu naa sọ.

Leave a Reply

%d bloggers like this: