Farouk Yahaya, ọga ṣọja tuntun, bẹrẹ iṣẹ

Olori awọn ṣọja ilẹ wa tuntun, Farouk Yahyah, ti Aarẹ Buhari ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii ọga ṣọja tuntun bẹrẹ iṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Aarọ kutu lo ti lọ si ọfiisi, ṣugbọn ko si eto fifa isakoso ileeṣẹ ologun le e lọwọ bo ṣe yẹ ko waye, boya nitori pe ẹni to yẹ ko ṣe bẹẹ to ti ku ni, ko sẹni to le sọ. Awọn ọga ṣọja kan lo tẹle ọkunrin yii.

Bẹẹ lo wọle lati ṣepade idakọnkọ pẹlu olori awọn ologun patapata nilẹ wa, Ọgagun Lucky Irabor.

Bakan na lo ṣepade pẹlu awọn lọgaa lọgaa mi-in nileeṣẹ ologun.

Inu ikọ ọmọ ogun ti wọn n pe ni Rgular Course ni ọga ṣọja tuntun yii wa ki wọn too yan an sipo.

Leave a Reply

%d bloggers like this: