Awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan ṣewọde l’Oṣogbo, wọn ni ki Buhari kọwe fipo silẹ

Florence Babaṣọla, Osogbo

Agbarijọpọ ẹgbẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan nipinlẹ Ọṣun, Osun Civil Societies Coalition, ti ke si Aarẹ Buhari lati kọwe fipo to wa silẹ to ba mọ pe nnkan ti daru mọ oun lọwọ.

Lasiko ifẹhonu han alaafia ti wọn ṣe niluu Oṣogbo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn eeyan ọhun ti sọ pe ara ko ti i ni awọn eeyan orileede yii to bayii ri, bẹẹ nijọba si kọ iha ko-kan-mi si ọrọ naa.

Ọkan lara wọn, Comrade Waidi Saka, ṣalaye fun ALAROYE pe ọkan pataki lara majẹmu ti aarẹ da pẹlu awọn ọmọ orileede Naijiria lọjọ ti wọn n ṣebura fun un ni lati daabo bo ẹmi ati dukia wọn, ṣugbọn nnkan ko ri bẹẹ mọ, ko sẹni to le sọ boya oun yoo pada wọle to ba jade ninu ile.

O sọ siwaju pe eto aabo ti buru lorileede yii, ko si si aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu. O fi kun ọrọ rẹ pe eto ọrọ-aje naa ti dẹnu kọlẹ, ti inira si pọ fun awọn araalu. O ni igba akọkọ niyi ti owo ẹwa yoo ga soke ju owo irẹsi lọ lọja, ti ṣiṣẹṣiṣẹ waa da bii ọlẹ, ti ọmọ ẹlẹran si n jeegun.

Ninu ọrọ tirẹ, Alhaji Waheed Lawal sọ pe ohun to niyi bayii ni fun Aarẹ lati kọwe fipo silẹ ko too di pe awọn araalu yoo fọn soju titi lati fẹhonu han.

Lawal sọ siwaju pe ikilọ ni iwọde wọọrọwọ to waye lọjọ Aje yii jẹ, ṣe lawọn si fi fa ileeṣẹ Aarẹ leti lati mọ pe nnkan ko rọgbọ fawọn araalu, o ni iwọde nla ṣi n bọ ti nnkan ba n ba bayii lọ.

O waa ke si awọn araalu lati mọ pe ọna kan ṣoṣo ti wọn le fi gba ara wọn lọwọ ijọba alai-naani ẹmi araalu yii ni ki wọn jade sita fẹhonu han, ki wọn ma ṣe da a da awọn ẹka kan rara.

Leave a Reply