Emi o sọ pe mo fẹẹ ba ti Iyabọ Ojo ati Nkechi Blessing jẹ o- Jide Kosọkọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Nigba ti Elenpe akọkọ sọrọ ti ko la a, to ni igba wuwo ju awo lọ, lai sọ boya igba gbigbẹ ni tabi tutu, kinni ọhun di ọran si i lọrun lo fi dowe doni.

Ipade tawọn agba ẹgbẹ TAMPAN ẹka Ẹko ṣe lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii, lori ọrọ Baba Ijẹṣa lo di ọran si Ọmọba Jide Kosọkọ to n ka alaye ẹgbẹ naa jade lọrun.

To dohun tawọn eeyan bẹrẹ si i sọko ọrọ lu agba oṣere naa nitori Iyabọ Ojo ati Nkechi Blessing. N l’Ọmọba ba sare jade ṣe fidio alaye, eyi lohun ti ‘Ofidoma’ bi wọn ṣe tun maa n pe Jide Kosọkọ sọ

“  Akọkọ na, ki i ṣe pe a fi ipade ta a ṣe ṣatilẹyin fun Baba Ijẹṣa, emi funra mi paapaa ko fara mọ ifipabanilopọ, kawọn eeyan yee ro pe a fara mọ ohun t’Ijẹṣa ṣe ni.

“ A o si sọ pe bi Iyabọ Ojo ṣe loun yoo ja fun ọmọbinrin to n ja fun ko tọna, ohun ta a sọ ni pe ko yee sọrọ nipa ẹ mọ lorukọ ẹgbẹ, ko fi i silẹ fun ile-ẹjọ lati ṣiṣẹ ẹ. Bẹẹ naa la dẹ tun kilọ pe ko yee tori ẹṣẹ ẹnikan sọrọ sawọn eeyan mi-in ti wọn jẹ TAMPAN. O tan.

“Ẹyin tẹ ẹ n sọ pe mo ni mo maa ba tiẹ ati ti Nkechi Blessing jẹ, ẹ o ṣe beere alaye na, ẹni to ṣee ba sọrọ ni mi, ti ma a dẹ ṣalaye ẹ daadaa. Mi o sọ pe mo fẹẹ ba tẹnikẹni jẹ tabi pe mo fẹẹ fin wọn lapẹ ti wọn maa fi kuro ninu tiata. Ṣebi ọmọ wa ni wọn jẹ, mo kan fohun akin sọrọ lati fidi ẹ mulẹ ni.

“Bi baba ba loun yoo gba ọmọ oun loju, ko ni i foju ọhun riran mọ, ṣe o tumọ si pe yoo gba a loju ọhun bẹẹ loootọ ni, ṣebi kọmọ le fi tun iwa ara ẹ ṣe ni, ko si baba ti yoo fẹ kọmọ ẹ fọ loju nitori ibawi.

“Ẹni to ba mọ ọ́n ki i wo o, awa naa ṣaa nipa ninu idagbasoke awọn ọmọ yii nidii iṣẹ, a o tun le lọwọ si ifasilẹ wọn. Emi o lagbara lori ara mi o, ka ma ti i sọ lori eeyan, Ọlọrun lalagbara.”

Alagba Kosọkọ sọ pe ọdun kẹtadinlọgọta (57) toun ti n ṣe tiata ree, nigba tawọn ọga awọn igba kan ko tiẹ fẹẹ gba awọn ọmọde, o loun ja raburabu to fi di pe awọn ọjẹwẹwẹ bẹrẹ si i forukọ silẹ, to si fi wa bẹẹ titi doni, ṣe asiko yii loun yoo wa fẹẹ gbogun ti ọmọ ọlọmọ.

Lakootan ọrọ naa, baba yii sọ pe ohun tawọn eeyan yi mọ oun lọwọ yii, ti wọn n sọko ọrọ lu oun lori ayelujara ko ruju rara. O ni bi wọn ba lọ sori ikanni Instagraamu oun, wọn yoo ri ohun ti ẹgbẹ fẹnu ko si naa toun gbe e sibẹ. Ohunkohun to ba yatọ si eyi, ero ọkan ẹlomi-in lapo ara rẹ ni, toun kọ, ti TAMPAN si kọ.

Ko sohun to tun fa họuhọu yii ju ọrọ Baba Ijẹṣa naa lọ. Ṣe ẹgbẹ TAMPAN darukọ Iyabọ Ojo ati Nkechi ninu ipade ti wọn ṣe lọjọ Satide to kọja naa, wọn si kilọ fun wọn pe ki wọn sinmi lori ọrọ Ijẹṣa, gbogbo a n ba ara ẹni ja lori ọrọ ọlọrọ gbọdọ dopin, ki wọn jẹ ki kootu ṣiṣẹ ọwọ ẹ.

Ọmọba Jide Kosọkọ lo ka awọn ikilọ ẹgbẹ tuntun naa jade, iyẹn lo fa a ti Iyabọ Ojo naa fi ṣe fidio alaye tiẹ nirọlẹ ọjọ Satide yẹn naa, to loun ko ba ija wa, alaye loun fẹẹ ṣe.

Ṣugbọn Nkechi Blessing ko ṣe tiẹ ni alalaye, niṣe lo ni boun ba tu aṣiri Jide Kosọkọ to n darukọ oun yẹn sita, oju buruku yoo gba awọn ọmọ rẹ obinrin ti.

O ni kawọn ṣi maa wo o, ṣebi Jide fẹẹ fi aye ni oun lara ni, oun naa ti ṣetan fun un.

Fidio Nkechi lo fa a tawọn eeyan fi n sọrọ ranṣẹ si Alagba Jide Kosọkọ, ti wọn ni boya o ti lo Nkechi sẹjẹ nigba tiyẹn n judi kiri lokeṣan, to n wa ki wọn sọ oun di staa dandan.

Ọpọ ọrọ abuku lo kun ori ayelujara nitori iṣẹlẹ yii, tawọn eeyan n ju u lu awọn to kan. Bẹẹ, ọrọ Baba Ijẹṣa naa lo bi Ige to bi Adubi mọ wọn lọwọ, to dohun to n ta ba’raale ta b’ara oko.

 

Leave a Reply