Faith Adebọla, Eko

 Ẹni to ba ri ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ka, Aminu Al-Amin, nibi to ti n tu awọn ina tijọba fi ṣe ẹṣọ si ọgba ti wọn kọ kaakiri ipinlẹ Eko, eeyan aa kọkọ ro pe boya kọngila to fẹẹ tun wọn ṣe ni, paapaa pẹlu bo ṣe mura bii awọn oṣiṣẹ ina, ṣugbọn ole paraku lọkunrin yii, ko tun ina ṣe, niṣe lo n ji awọn eroja ina naa lọ.

Ọjọruu, Wẹsidee ọsẹ yii, lọwọ palaba rẹ segi nigba tawọn kan fura si bo ṣe n tu awọn giloobu ati gilaasi ti wọn fi ṣe awọn ina naa sinu baagi to gbe wa, wọn si ṣakiyesi pe ko da wọn pada, niṣe lo kan n re wọn lori lọ, lawọn to ri i ba ke sawọn agbofinro to wa nitosi.

Ọgba Alfred Rewane Beautiful Garden, to wa lọna Osborne, Ikoyi, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, ni Aminu ti lọọ ṣiṣẹẹbi ọhun, awọn ẹṣọ ajọ to n ri si imọtoto ayika nipinlẹ Eko, Lagos State Environmental Sanitation Corps ti wọn wa n ṣiṣẹ lagbegbe Ikoyi si Ọbalende, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, ni wọn waa fi pampẹ ofin gbe e.

Wọn ni bi wọn ṣe sun mọ ọn, ti wọn bi i pe bawo lo ṣe jẹ to fi n tu awọn ina naa, o purọ pe oṣiṣẹ to n tun ina ṣe loun, oun fẹẹ lọọ ṣatunṣe sawọn nnkan toun tu naa lọfiisi awọn ni, ati pe oun maa da wọn pada laipẹ.

Ṣugbọn nigba ti wọn beere pe ko mu kaadi idanimọ rẹ  ati iwe tijọba fi fun un laṣẹ ohun to n ṣe yii wa, niṣe lakara tu sepo, ti ọrọ si pesi jẹ.

Wọn lawọn kan ti wọn mọ afurasi ọdaran yii sọ pe awọn ti maa n ṣalaabapade ẹ nibi to ti maa n ta awọn eroja ina naa ni gbanjo, l’Ekoo.

Wọn lọkunrin naa jẹwọ nigba ti wọn din dundu iya fun un diẹ pe loootọ loun waa jale ni, ati pe aṣọ toun wọ ni ko jẹ ki wọn ti ri oun mu ṣaaju tori awọn eeyan yoo ro pe oṣiṣẹ ina gidi ni loootọ.
Wọn ni wọn ti fa Aminu le awọn agbofinro lọwọ fun iwadii, wọn si ti ko ẹru ijọba to n ja lole fawọn ọlọpaa gẹgẹ bii ẹri.

Leave a Reply