Layaajọ ọdun Ileya, Aṣiwaju Tinubu gbadura fawọn alaṣẹ ilẹ wa

Faith Adebọla

Layaajọ ayẹyẹ ọdun Ileya, gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Hammed Tinubu, ti gbadura fun gbogbo awọn alaṣẹ ilẹ wa pe Ọlọrun yoo fun wọn ni ẹmi ọgbọn lati le bori asiko ta a wa yii. O sọrọ naa ninu atẹjade kan to fi ranṣẹ ikini ku ọdun.

Ninu atẹjade naa lo ti gbadura fun awọn ṣọja ati ileeṣẹ oloogun yooku ti wọn wa loju ogun, ti wọn n ja fun ilẹ wa lori eto aabo to mẹhẹ bayii. Bẹẹ naa lo gbadura fun Aarẹ ilẹ wa, awọn gomina ati gbogbo awọn adari yooku pe ki Ọlọrun fun wọn ni oore-ọfẹ lati la asiko ipenija eto aabo yii ja.

Bakan naa lo rọ awọn eeyan lasiko ọdun yii pe bi wọn ṣe n ṣe pọpọṣinṣin ọdun yii, ki wọn ranti awọn ti ko ni, ki wọn si nawọ ifẹ si wọn.

Tinubu ni, ‘’Lati jẹ Musulumi ododo pe fun ki eeyan jẹ ẹni to lawọ, to si n ranti awọn alaini. Ipenija ti a n koju gẹgẹ bii ọmọ orileede yii lọwọlọwọ paapaa pe fun ka mu aṣẹ Allah ṣẹ nipa riranti awọn ti ko ni, ki a si fi fun wọn, ki a le ni awujọ to dara, ati eyi ti a fẹ lọkan.’’

Tinubu tun lo asiko naa lati gbadura fun iṣọkan ati iduroṣinṣin orileede yii. Bẹẹ lo tun gbadura fun Aarẹ ile wa, awọn gomina atawọn to di ipo aṣẹ mu yooku atawọn ologun to n doju ija kọ awọn afẹmiṣofo nilẹ wa.

Leave a Reply