Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Boya Bọlanle Aworetan Ọmọjuwa ko ba mọ ko ma wale, iba jẹ pe obinrin to n gbe lorilẹ-ede United Kingdom naa mọ pe wọn yoo yinbọn pa oun ni Naijiria ni, iba ma wale waa ṣoku iya ẹ. Afi bo ṣe wale tan tawọn agbebọn yinbọn pa a l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ni marosẹ Eko s’Ibadan.
Ohun ti a gbọ ni pe ọsẹ to kọja lọhun-un ni ayẹyẹ oku iya obinrin yii waye. Gẹgẹ bii ọmọ rere to gbẹyin iya rẹ, ti ko si fẹẹ fowo ranṣẹ sile lasan lai fun iya naa ni ẹyẹ ikẹyin nipa yiyọju sile, Bọlanle kuro ni UK to n gbe, o wa si Naijiria lati sin iya rẹ, ayẹyẹ naa si lagbara gidi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.
Gbọngan ayẹyẹ ti wọn n pe ni Civic Centre, to wa ni Victoria Island, nipinlẹ Eko, ni ayẹyẹ oku naa ti waye lọsẹ to kọja, gbogbo awọn alaabaṣẹ to jẹ ọrẹ ọmọlooku nilẹ yii ati loke okun naa ni wọn si waa ba a ṣẹyẹ fun iya rẹ.
Ọjọ Alamisi to kọja yii ni ara ilu oyinbo to waa ṣoku iya rẹ yii ni oun fẹẹ de ilu Ọyọ lẹyin ayẹyẹ naa, lati ṣe awọn nnkan to yẹ ni ṣiṣe ko too pada lọ.
Afi bi wọn ṣe de ọgangan ile Guru Maharaji, ni marosẹ Eko s’Ibadan, ti awọn agbebọn kan yọ lati ibi ti ẹnikan ko mọ, ti wọn si da ibọn bo Bọlanle Aworetan Ọmọjuwa, niṣoju awọn ọmọ rẹ ti wọn jọ n rin irin ajo, wọn pa obinrin ti ọjọ ori rẹ ko to nnkan naa danu raurau.
Iku ojiji to pa Bọla yii ṣi n da bii ala loju awọn eeyan rẹ nilẹ yii ati loke okun to ti wa ni. Kaluku n sọ pe ṣe bayii naa ni Naijiria yii buru to, ti wọn n dana ibọn bo eeyan lọsan-an gangan lai si ibẹru kankan.
Ọpọ eeyan lo n sọ pe ki Bọla mọ ko ma wale, awọn aṣẹnilori to ran an tẹle iya rẹ yii ko ma ba ri nnkan kan fi i ṣe. Ṣugbọn bẹẹ naa lawọn eeyan mi-in n sọ pe ko si laburu ninu kọmọ wale waa sin iya rẹ, wọn ni bo ṣe yẹ ko ri gan-an niyẹn.
Wọn ni Naijiria lo di ilu ti ko si aabo fun araale atawọn ara ilu oyinbo, to fi di pe wọn n yinbọn paayan lọsan-an gangan. Afi ki eto aabo jẹ ijọba wa logun nikan si ni nnkan fi le yipada, ai jẹẹ bẹẹ, awọn agbebọn, ajinigbe, adigunjale atawọn oniṣẹ ibi yooku ko ni i yee ika i ṣe.