Ikọlu ileewe awọn ologun: Buhari fẹẹ sọ Naijiria di Afghanistan ni o-SOKAPU

Awọn eeyan agbegbe Iwọ Oorun Kaduna ti wọn n pe ni Southern Kaduna Peoples Union ti sọ pe pẹlu bi awọn agbebọn ṣe kọ lu ileewe awọn ologun ni Kaduna, ti wọn pa awọn meji, ti wọn si tun ji ẹni kan gbe sa lọ ti wọn ko ti i ri i di ba a ṣe n sọ yii, o ti han gbangba pe niṣe ni Buhari fẹẹ sọ Naijiria di orileede Afghanistan.

Agbẹnusọ awọn ẹgbẹ ti wọn n pe ni SOKAPU yii, Lukat Binniyat, sọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu iweeroyin Punch pe pẹlu bi aya ṣe ko awọn eeyan naa, ti wọn ya wọ inu ọgba ileewe awọn ologun ọhun, ti ko si si eyikeyii ninu awọn agbebọn naa ti wọn ri mu, tabi to ku, ti ẹnikẹni ninu wọn ko ṣi ṣeṣe fi han pe ninu ewu nla ni ijọba awa-ara-wa ti a n ṣe ni Naijiria wa.

O fi kun alaye rẹ pe bi awọn janduku naa ṣe ya wọ ileewe awọn ologun yii, ti wọn pa eeyan meji, ti wọn si ji ẹni kan gbe sa lọ ko jọ oun loju rara. O ni wọn ti figba kan ṣe akọlu si baraaki wọn ati ileewe awọn olukọ (Staff College), to wa ni Jaji, laarin Zaria si Kaduna nigba bii meloo kan ninu ọdun yii, ti wọn si ko ẹran ọsin atawọn nnkan mi-in lọ.

Lukati ni iṣẹlẹ yii yoo fi han gbogbo araalu pe yatọ si Buhari, awọn ọga ologun atawọn gomina, inu ewu ni gbogbo awọn to ku niluu wa, wọn si wa lọwọ awọn eeyan ti ko bọwọ fun ofin, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati gbakoso Naijiria.

‘‘A wa n fi asiko yii pe gbogbo awọn Musulumi ti ki i ṣe alakatakiti, awọn Onigbagbọ ati gbogbo awọn akin ọkunrin to ni igboya, lati dide ni iṣọkan, ki wọn si kọ iwa ailojuti to n ṣẹlẹ yii, ki wọn si pe Buhari ati Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, lati jigiri si ojuṣe wọn ka too tun ri jinna si isalẹ patapata ta a wa yii.’’

 

Leave a Reply