Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi ohun gbogbo ba lọ bo ṣe yẹ, ko le pẹ rara ti ijọba ipinlẹ Ogun naa yoo fi maa gba owo-ori ọja funra wọn, ti wọn yoo gba kinni naa kuro lọwọ ijọba apapọ. Nitori lọjọ kan naa ti awọn aṣofin jokoo lori aba ọhun l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, gbogbo ile pata lo fọwọ si i pe kijọba apapọ yee gba owo naa ti wọn n pe ni VAT, wọn ni ẹtọ ijọba ipinlẹ ni.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021, ni wọn jokoo apero lori aba owo-ori ọja naa.
Lọjọ yii kan naa ni wọn si fohun ṣọkan labala kin-in-ni ati ikeji (First and second reading) pe ijọba ipinlẹ Ogun lawọn fẹ ko maa gba owo-ori ọja naa bayii, gẹgẹ bii Eko ati Rivers naa ṣe yari mọ ijọba apapọ lọwọ.
Awọn aṣofin Ogun sọ pe gbogbo ara lawọn fi mọ ofin naa ti wọn pe akọle ẹ ni H.B NO.73/OG/2021.
Wọn ni ofin ti yoo jẹ ki ipinlẹ yii mọ iye to tọ si i lori owo ti wọn n pa funjọba apapọ ni, yoo si tun gbe ipinlẹ Ogun si ipo gidi to yẹ ko wa, nitori yoo le ṣakoso iṣuna rẹ funra rẹ.
Bẹẹ lawọn aṣofin kan sọ pe kinni ọhun ko gbọdọ pẹ rara ti yoo fi bẹrẹ nipinlẹ Ogun, nitori atunto tawọn ti n beere fun, tijọba apapọ ko fẹẹ gbọ, lo wọle de wẹrẹ yii, wọn ni ko mu tọwọ ẹ wa ko gbọdọ gba tọwọ ẹ ni.
Nigba to n fesi, olori ile- igbimọ aṣofin Ogun, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, dupẹ lọwọ awọn eeyan rẹ fun atilẹyin wọn lori aba yii. Lẹyin igba naa lo gbe aba naa fun ẹka to n ri si iṣuna nile naa, o si kede pe ipade ita gbangba lori aba yii yoo waye l’Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021.