Awọn oṣiṣẹ-fẹyinti fẹhonu han nipinlẹ Ogun, wọn nijọba n fiya jẹ awọn lọjọ ogbo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

A ki i ti ọwọ to n dun ni bọ abẹ aṣọ ni awọn baba ati iya agbalagba ti wọn ti ṣiṣẹ sin ijọba ipinlẹ Ogun ti wọn si ti fẹyinti, fi ọrọ wọn ṣe laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an yii, wọn ko wo ti ojo to n rọ, wọn ya bo ọfiisi Gomina Dapọ Abiọdun l’Oke-Mosan, nitori owo ifẹyinti ati ajẹmọnu wọn ti wọn ni ijọba ko san.

Niṣe lawọn mi-in tẹni silẹ, ti wọn sun le e lori lẹnu geeti ọfiisi ijọba ipinlẹ yii, awọn mi-in ko si tẹ nnkan kan silẹ ti wọn fi jokoo, ti wọn ni lọjọ naa gan-an lawọn yoo yanju iṣoro awọn.

Awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ṣiṣẹ labẹ ijọba ibilẹ lawọn eeyan naa, wọn si ṣalaye pe ẹgbẹrun mẹta naira pere lawọn mi-in ṣi n gba ninu awọn gẹgẹ bii owo ajẹmọnu (pension) loṣu, bẹẹ lawọn mi-in ko ti i ri owo ifẹyinti wọn ti i ṣe gratuity gba lẹyin ọdun rẹpẹtẹ ti wọn ti fẹyinti.

Nigba to n sọrọ nipa iye gbese tijọba jẹ wọn, Alaga awọn oṣiṣẹ fẹyinti labẹ ijọba ibilẹ, ‘Local Government Pensioners Association of Nigeria’( LOGPAN), Alagba Sikiru Ayilara, fi aidunnu ṣalaye pe Gomina Dapọ Abiọdun ko mu ileri to ṣe fawọn ṣẹ. O ni ẹgbẹrun mẹta lawọn ẹlomi-in gba lodidi oṣu kan lẹyin ti wọn ti fi ọdun rẹpẹtẹ sinjọba.

Ayilara ṣalaye pe miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira (500m) tijọba Ogun n san ni kọta kọọkan fawọn oṣiṣẹ-fẹyinti kere pupọ, o ni ko ka nnkan kan.

Baba yii sọ pe ọdun mẹrinlelọgbọn ni yoo gba ijọba lati san gbese biliọnu mejidinlaaadọrin(68bn),ọwọ ọdun mẹwaa ti wọn jẹ awọn, bi wọn ba n san ẹẹdẹgbẹta miliọnu ni saa kọọkan bi wọn ṣe n san an yii. Ta lo si fi da awọn loju pe ẹmi awọn yoo ṣi wa titi digba naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko jẹ kawọn oṣiṣẹ-fẹyinti naa wọle sinu ọgba ijọba, awọn eeyan naa gbe patako oriṣiiriṣii dani, ninu ẹyi ti wọn kọ akọle si pe, ‘’Gomina Dapọ Abiọdun, tẹle ọrọ baba rẹ ko o tọju awa oṣiṣẹ-fẹyinti,  ohun to n ṣẹlẹ yii ko tọ si wa rara, wọn n ta owo ifẹyinti wa fun wa ni’’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn baba ati mama agba yii sọ pe awọn fẹ kijọba fi kun owo ajẹmọnu awọn, ki wọn si ṣafikun si ẹẹdẹgbẹta miliọnu onikọta kan yii, kowo ọhun si maa jẹ sisan lasiko to yẹ.

Wọn tun ni awọn ko fẹ bo ṣe jẹ ileeṣẹ eto iṣuna lo n sanwo awọn, wọn ni kijọba gbe e fun ẹka to n ri si owo ifẹyinti labẹ ijọba ibilẹ.

Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi, to ba awọn eeyan naa sọrọ, rọ wọn pe ki wọn ma binu.

O ni omi lo pọ ju ọka lọ funjọba lasiko yii, eleti gbaroye ni Gomina Dapọ Abiọdun, yoo si boju wo ọrọ wọn laipẹ jọjọ.

Leave a Reply