Awọn agbẹ fa ibinu yọ l’Ọgbẹṣẹ, wọn lawọn Fulani darandaran ti ba ire oko awọn jẹ tan

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn eeyan ilu Ayede Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, ti fẹdun ọkan wọn han lori bawọn Fulani darandaran ṣe n ba awọn nnkan ọgbin oko wọn jẹ pẹlu ẹran ọṣin ti wọn n da.

Pẹlu ibinu lawọn eeyan ọhun fi ko ara wọn jọ siwaju aafin Alayede tilu Ọgbẹṣẹ laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ ayajọ ominira, nibi ti wọn ti fẹhonu han, ti wọn si ke sijọba Gomina Rotimi Akeredolu lati tete wa nnkan ṣe sọrọ awọn Fulani to fẹẹ sọ awọn di ẹdun arinlẹ lagbegbe naa.

 

Ọkan ninu awọn oloye ilu, Oloye Simon Oduh, ati Sunday Abi to gbẹnu awọn araalu sọrọ ni ọkan-o-jọkan ipade lawọn ti ṣe pẹlu ẹgbẹ darandaran ti wọn n pe ni Miyetti Allah, ṣugbọn tawọn Fulani ki i tẹle adehun ti awọn ba jọ ṣe.

Bakan naa ni wọn ni gbogbo ofin ati ilana ifẹranjẹko tijọba ṣẹṣẹ buwọ lu ko di awọn bororo to wa lagbegbe Ọgbẹṣẹ lọwọ ninu isẹ ibi ti wọn n ṣe.

Awọn eeyan ọhun ni awọn ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ atawọn fijilante lati gbeja ara awọn tijọba ba kuna lati gbe igbesẹ kiakia lori ọrọ awọn Fulani naa.

Nigba to n kin ọrọ awọn araalu rẹ lẹyin, Adele Ọba ilu Ọgbẹṣẹ, Ọmọọba Bukọla Akinyẹde, ni ko si arufin laarin awọn eeyan ti oun n dari, o ni oun mọ pe awọn Fulani darandaran lo fẹẹ sun wọn kan ogiri.

Ọmọọba Akinyẹde rọ awọn olufẹhonu han ọhun lati mu suuru diẹ si i, o loun ti fi iṣẹlẹ naa to kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo pẹlu alaga ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ leti.

Leave a Reply