N’Ileṣa, awọn araadugbo dana sun obinrin alarun ọpọlọ to ṣa awọn alajọgbele rẹ meji pa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Obinrin kan ti wọn sọ pe o ni arun ọpọlọ, Esther Adu, la gbọ pe awọn ọdọ ti inu n bi lagbegbe Ita Balogun, niluu Ileṣa, ti dana sun bayii latari pe o ṣa awọn alajọgbele rẹ meji pa.

Adu, ẹni ọdun marundinlọgọta, la gbọ pe o mu ada, to si bẹrẹ si i ṣa awọn mẹta ti wọn jọ n gbenu ile, awọn meji ku loju-ẹsẹ, ti ẹni kẹta si n gbatọju lọwọ nileewosan.

A gbọ pe Adu ṣa Ojuọlape Olojo, ẹni aadọrun-un ọdun ati Samson Sunday, ẹni aadọrun-un ọdun ti wọn jọ n gbenu ile ni Ita Balogun ladaa, ti awọn yẹn si ku loju-ẹsẹ.

Bakan naa lo ṣa Disu Ọlalẹyẹ, ẹni aadọrun-un ọdun ladaa, ṣugbọn ti iyẹn n gbatọju lọwọ nileewosan kan.

Ẹnikan to n gbe Ita Balogun, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun, ṣalaye fun ALAROYE pe ileewosan aladaani kan lagbegbe Ijofi, ni Diṣu ti n gbatọju lọwọ.

Ọkunrin yii ṣalaye pe nigba ti awọn araadugbo ri nnkan ti Adu ṣe ni wọn dana sun un ko too di pe awọn ọlọpaa de.

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, o ni iwadii ti bẹrẹ lori rẹ.

Leave a Reply