Awọn oloye Ikẹrẹ-Ekiti fariga, wọn lawọn ko ni i gba Olukẹrẹ gẹgẹ bii ọba

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn oloye ati igbimọ to n ṣejọba pẹlu Ogoga Ikẹrẹ-Ekiti ti fariga, wọn faake kọri pe laye, awọn ko ni i gba Olukẹrẹ gẹgẹ bii ọba niluu naa.

Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja yii, ni ijọba ipinlẹ Ekiti fi ọba tuntun, Ọba Ganiyu Ọbasoyin, jẹ ni Odo-Ọja, Ikẹrẹ-Ekiti.

Odo-Oja yii lo wa labẹ Ikẹrẹ-Ekiti, to si ti n lakaka lati gbomonira kuro labẹ Ikẹrẹ-Ekiti lati ọdun 2014, ṣugbọn ti ijọba asiko naa labẹ gomina tẹlẹ, Ọgbẹni Ayọ Fayoṣe, ko fun wọn ni ominira.

Igbesẹ ti ijọba Ekiti gbe lọjọ Ẹti, Furaide yii, lo fopin si awuyewuye ati rogbodiyan lori ọrọ fifi ọba jẹ to ti wa niluu naa lati ọdun 2014 ọhun.

Ninu iwe ifẹhonu han kan ti igbimọ iṣejọba Ogoga, eyi ti wọn pe ni (Ogoga-in-council) kọ, ti Oloye Olufẹmi Babatọla to jẹ Sapetu ilu Ikẹrẹ-Ekiti ati awọn oloye mẹẹẹdogun mi-in fọwọ si sọ pe eewọ patapata ni fifi Olukẹrẹ jẹ niluu naa.

Awọn oloye naa ninu iwe ifẹhonu han yii sọ pe gbogbo ilu naa ko ni i gba ki Odo-Ọja to wa labẹ Ikẹrẹ-Ekiti da duro lati ni ọba tiwọn, wọn ṣalaye pe Odo-Ọja jẹ adugbo kan lara Ikẹrẹ-Ekiti.

Iwe ifẹhonu han yii ti awọn Oloye mẹrinlelogun fọwọ si juwe igbesẹ Gomina Kayọde Fayẹmi gẹgẹ bii ọna kan pataki lati gbẹsan bi gomina naa ṣe fidi-rẹmi niluu naa ninu eto idibo gomina lọdun 2018, eleyii ti ọmọ bibi ilu naa to tun jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti nigba naa, Ọjọgbọn Kọlapọ Ẹlẹka, jawe olubori niluu ọhun.

Wọn fi kun un pe ilu naa ti gba ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Ekiti lọ lati pe ijọba lẹjọ, ati lati ta ko igbesẹ naa. Agbẹjọro agba ati gomina ipinlẹ naa yoo jẹ olujejọ ninu iwe ipejọ naa.

Wọn sọ pe gbogbo ilakaka ati ipinnu ijọba ipinlẹ Ekiti lati doju aṣa ati iṣe ilu naa bolẹ ko ni i duro, wọn ṣalaye pe Odo-Ọja, nibi ti Fayẹmi ti fi ọba jẹ yii ti ni oloye kan ti wọn n pe ni Ọlọgọtun tẹlẹ.

Nigba ti wọn n tan imọlẹ miiran si ọrọ naa, awọn oloye yii sọ pe igbimọ awọn ọba ipinlẹ Ekiti ti kọkọ juwe ipo Olukẹrẹ gẹgẹ bii oloye lasan lọdun 2014. Bakan naa nijọba asiko naa tun juwe ipo Olukẹrẹ gẹgẹ bii olori olooṣa niluu naa.

Leave a Reply