Oṣiṣẹ ijọba meji wọ gau l’Ondo, ọmọ were ni wọn ta ni gbanjo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Meji lara awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo, Sarumi Adeyẹmi ati Orisamẹhin Florence, ni wọn ti wa ni ahamọ awọn agbofinro lori ẹsun lilu ọmọ were kan ta ni gbanjo.

Awọn mejeeji yii la gbọ pe wọn jẹ ọga agba nileesẹ to n ri sọrọ awọn obinrin nipinlẹ Ondo.

ALAROYE gbọ pe obinrin ọlọdẹ ori kan ti wọn porukọ ẹ ni Deborah Iretioluwa Ọlọrundare lo bimọ sita gbangba niyana Oduduwa, eyi to wa lagbegbe Kọlẹẹji Adeyẹmi, to wa niluu Ondo, nidaaji ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja.

Bi ilẹ ọjọ naa ṣe n mọ lawọn alaaanu kan sare sugbaa iya ọmọ tuntun naa lai wo ti ailera rẹ, ti wọn si gbe e lọ si ileewosan ijọ Aguda to wa nitosi ibi to bímọ si fun itọju to peye.

Ninu alaye ti aṣoju ijọba, Bunmi Koyẹnikan, ṣe fawọn oniroyin nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni lẹyin ti iya ọmọ ọhun ti gba itọju diẹ nileewosan ti wọn kọkọ gbe e lọ l’Ondo ni wọn fi i ṣọwọ sile-iwosan ti wọn ti n tọju awọn alarun ọpọlọ, eyi to wa loju ọna Ọda, l’Akurẹ.

O ni lati igba to ti bẹrẹ si i gba itọju l’Ondo lawọn ti kan si ileesẹ to n ri sọrọ awọn obinrin lati fi ohun to ṣẹlẹ̀ to wọn leti.

Lati igba naa lo ni wọn ti yọnda ọmọ to bi naa fun wọn pẹlu adehun pe wọn gbọdọ maa gbe e waa ki iya rẹ lẹẹkọọkan, nitori pe o ṣee ṣe ki ara rẹ tete ya to ba n ri ọmọ rẹ loorekoore. Ṣugbọn niṣe ni wọn kọ ti wọn ko gbe ọmọ naa waa ki iya rẹ gẹgẹ bii ọrọ àjọsọ wọn.

Obinrin ọlọdẹ ori ọhun ko pẹ pupọ nileewosan ti Ọlọrun fi gbọ adura rẹ, ti ara rẹ si ya, lẹyin eyi lo bẹrẹ si i beere ọmọ rẹ, ṣugbọn ti ko sẹni to da a lohun.

Nigba ti wahala obinrin yii fẹẹ pọ ju lawọn oṣiṣẹ naa ba lọ si ile awọn ọmọ alainiyaa kan to wa loju ọna Ondo, l’Akurẹ, nibi ti wọn ti lọọ mu ọmọkunrin alaabọ ara kan, eyi ti wọn lọọ gbe fun Deborah gẹgẹ bii ọmọ rẹ, laimọ pe arun ọpọlọ to ni nigba naa ko di i lọwọ mọ lati da ọmọ tirẹ mọ.

Bi wọn ti gbe ọmọ de ọdọ rẹ lo yari mọ wọn lọwọ to si n jẹ ko ye wọn pe oun ṣi ranti daadaa pe ọmọbinrin loun bi, oun ko bi ọmọkunrin debi ti oun yoo bi alaabọ ara.

Ọrọ yii pada di ariwo, to si dohun tawọn agbofinro DSS n ba wọn da si, wọn bẹrẹ iwadii lẹyin ti wọn ti fi pampẹ ofin gbe awọn oṣiṣẹ mejeeji.

Wọn ko ti i ba iwadii ọhun jinna tí aṣiri fi tu sita pe ṣe ni wọn ta ọmọ tuntun naa fun obinrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Toyin Ọlanbiwọnninu ni miliọnu kan Naira.

Inu osu karun-un, ọdun 2020, ni wọn lobinrin to ṣi n woju Ọlọrun fun ọmọ ọhun kọkọ lọ si ileesẹ to n ri sọrọ awọn obinrin pe oun nilo ọmọ ti oun fẹẹ gba tọ.

Ibẹ ni wọn si ti dari rẹ sọdọ Sarumi ati Orisamẹhin, niwọn igba to jẹ pe awọn ni wọn wa nidii eto bi wọn ṣe n fi awọn ọmọ alainiyaa sita fawọn to fẹẹ gba ọmọ tọ lọdọ ijọba.

Wọn ní gbogbo iwe to yẹ lobinrin ta a n sọrọ rẹ yii fọwọ si, ti wọn si ṣeleri fun un pe awọn yoo kan si i ti ọmọ ba ti wa nilẹ.

Inu oṣu kẹwaa ni wọn ranṣẹ pe e pe ko tete maa bọ, ti wọn si gbe ọmọ Deborah le e lọwọ lẹyin to ti sanwo ti wọn ni ko san.

Awọn adari ileesẹ naa ti kọkọ paṣẹ gbele-ẹ fawọn afurasi mejeeji ki wọn too fa wọn le awọn agbofinro lọwọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Ohun ta a gbọ ni pe ọrọ awọn oṣiṣẹ mejeeji ti wọn fesun kan yii ti de ile-ẹjọ, ọjọ kẹfa, osu kọkanla, ni igbẹjọ yoo si bẹrẹ ni pẹrẹu lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Gbogbo igbiyanju awọn agbofinro lati fi panpẹ ofin gbe Abilekọ Ọlanbiwọnninu to ra ọmọ ni wọn ni ko ti i so eeso rere pẹlu bi wọn ṣe lobinrin ọhun ko si ni Naijiria mọ. Wọn ni bọwọ rẹ ṣe tẹ ohun to n wa lo ti tẹ ọkọ leti lọ soke okun, bẹẹ ni ko sẹni to ti i gburoo rẹ lati igba naa.

Leave a Reply