Ọlọpaa ti mu ọmọkunrin ti akẹkọọ Poli Iree ku sile rẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ agba ipinlẹ Ondo, Onidaajọ Williams Akintoroye, ti ṣagbekalẹ ile-ẹjọ tuntun meji ti yoo  maa gbọ gbogbo ẹsun iwa ọdaran to ba ti n waye nipinlẹ naa.

Kootu kẹfa ati ikeje ninu awọn kootu to wa ninu ọgba ile-ẹjọ giga to wa loju ọna Ọba Osupa, Akurẹ, ni wọn ti ya sọtọ fun gbigbọ ẹjọ awọn arufin lati asiko yii lọ.

Gẹgẹ ba a ṣe fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade ti Ọgbẹni Kọla Adeniyi to jẹ amugbalẹgbẹẹ fun kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ondo fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, o ni igbesẹ yii waye ki igbẹjọ awọn afurasi ọdaran to n lọ lọwọ lawọn ile-ẹjọ giga le ya kiakia latari.

O ni bi idajọ awọn arufin ṣe n falẹ, leyii to ṣokunfa bawọn ọgba ẹwọn ṣe n kun akunfaya ko dun mọ Amofin Charles Titiloye to jẹ kọmiṣanna ninu, idi ree to fi paṣẹ yiya ile-ẹjọ giga meji sọtọ, nibi ti igbẹjọ awọn ẹsun iwa ọdaran yoo ti maa waye lai fi akoko ṣofo mọ.

Ile-ẹjọ giga to wa ninu ọgba ẹwọn Olokuta, niluu Akurẹ, nikan lo ni wọn ti n ṣẹjọ awọn ọdaran tẹlẹ, ṣugbọn kootu meji ti wọn tun ṣẹṣẹ gbe kalẹ bayii yoo din wahala awọn ẹsọ alaabo atawọn tọrọ kan ku nigbakuugba ti igbẹjọ ba fẹẹ waye.

Adeniyi ni ki i ṣe pe awọn ile-ẹjọ giga yooku naa ko ni i maa gbẹjọ awọn arufin mọ awon ẹjọ ti wọn ba n ṣe, iyatọ to wa nibẹ ni pe awọn kootu mejeeji ti wọn ṣẹṣẹ ya sọtọ ko ni i maa gbọ ẹjọ mi-in ju ẹsun iwa ọdaran lọ.

Leave a Reply