Oluwoo ṣọdun Olodumare, o ni Musulumi ati Onigbagbọ ko gbọdọ jija ẹsin, ọmọ iya kan naa ni wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo ati Ọlawale Ajao, Ibadan

Apẹẹrẹ iroyin ibaṣepọ awọn ẹda Ọlọrun ninu ọgba Paradise ti wọn royin ninu Bibeli, pe awọn ẹda abijawara atawọn ẹda abiwapẹlẹ yoo dijọ jọ maa ṣere lai pa ara wọn lara, fara han niluu Iwo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pẹlu bi awọn Musulumi ati Krisitiẹni ti gbagbe ẹsin, ti wọn jọ n yin Ọlọrun Ọba to da wọn loju kan naa bii pe ọmọ ijọ kan naa ni wọn.

Nibi Ajọdun Olodumare lagbaaye to waye lọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, niṣẹlẹ ọhun ti waye laafin Oluwoo tilẹ Iwo, nibi ti awọn aafaa ti n kan ilu bandiri kẹkẹ sibadi awọn Krisitiẹni, ti awọn Musulumi paapaa si n jijo ihinrere Oluwa awọn ọmọlẹyin Jesu lai fi tẹsin ṣe.

Bi Oluwoo paapaa ṣe jẹ ẹni to gbe ẹsin Islaamu leri to, bo ṣe n kọrin awọn Musulumi lo n korin Krisitiẹni to si n jijo to ba ọkọọkan wọn mu.

Ohun to mu odidi Kabiesi maa jijo ajokara, ki lawọn ijoye atawọn araalu n duro ṣe, niṣe lawọn naa n fi gbogbo ara jo o, ẹlomi-in paapaa fẹẹ jijo ajotakiti, awọn Musulumi atawọn Onigbagbọ si n jo kolu ara wọn tẹrin-tọyaya lai binu sira wọn.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ alarinrin naa, Oluwoo tilẹ Iwo, Ọba Abdul Rasheed Adewale (Telu I), rọ awọn Musulumi ati Onigbagbọ lati jawọ ninu iwa ẹlẹsinmẹsi, o ni ọmọ iya kan naa ni wọn, nitori Ọlọrun kan naa ni wọn jọ n sin.

O fi kun un pe awokọṣe bo ṣe yẹ kawọn Musulumi ati Krisitiẹni maa bara wọn gbe pẹlu ifẹ ṣe gan-an lo n ṣẹlẹ nibi Ọdun Olodumare yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ siwaju, “Ẹ ma ṣe ki mi lonii, ẹni ba ki mi ti rufin. Onilu paapaa to ba filu ki mi ti janba adehun, mo si maa le iru onilu bẹẹ jade ni. Ọlọrun nikan ni kẹ ẹ maa ki lonii, nitori ọdun Olodumare la n ṣe lonii.

Awọn eeyan le maa beere pe ki lawa ta a pera wa ni Musulumi ati Kiristiẹni ro debi Ọdun Olodumare. Anabi Dauda ta a mọ si Ọba Dafidi ṣọdun Ọlọrun. To o ba gbọ ọ ri, o ti gbọ ọ lonii niyẹn.”

Nigba to n ta ko awọn to maa n pe awọn ọba n’Igbakeji Oriṣa, Ọba Adewale sọ pe “Atole Ọlọrun lorilẹ aye ati alaṣẹ lori oriṣa l’Ọlọrun ṣe awa ọba. Bi eeyan ba jẹ igbakeji oriṣa, oriṣa ni yoo maa ran iru ẹni bẹẹ niṣẹ nitori oriṣa lọga ẹ.

“Nibi ti mo si ba a de yii, emi kọja ẹni to tun le ṣe igbakeji, nitori naa, alaṣẹ lori oriṣa lemi, mi ki i ṣe igbakeji oriṣa. Ojo pa bata pa jinwinjinwin ẹni to ba pe mi nigbakeji orisa.

“Eyi nigba akọkọ ta a maa ri Musulumi ati Onigbagbọ ti wọn yoo jọ maa fifẹ han sira wọn bayii. Ọdọọdun bayii la oo si maa ṣajọdun Olodumare yii.”

Gbogbo ọba ilẹ Iwo atawọn ọba kaakiriri ipinlẹ Ọṣun titi dori Ọba Ọlatunbọsun Abdul Azeez Adebamiji ti i ṣe Akire ti Ikire,  atawọn ijoye ilu naa, eyi ti Alhaji Sikiru Atanda ti i ṣe Ọtunba ilẹ Iwo ko sodi, ni wọn peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa titi dori awọn ọmọ Iwo to ri taje ṣe lẹyin odi gbogbo.

Gbajugbaja obinrin olorin Musulumi nni, Alhaja Saidait Fatimo, ati Mega 99, pẹlu awọn akọrin ijọ Prayer Centre Church of God lati ipinlẹ Ondo ni wọn kọrin jo fawọn olukopa nibi ayẹyẹ alarinrin naa ti i ṣe akọkọ iru ẹ kaakiri agbaye.

 

Leave a Reply