Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti ni irọ ni ọrọ kan ti Arẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, iyẹn oloye iba Gani Adams, sọ lopin ọsẹ to kọja pe awọn ajinigbe ti waa fi ipinlẹ Kwara ati Kogi ṣe ibujoko wọn. Wọn ni irọ funfun balau ni, awọn ajinigbe ko si ni ipinlẹ Kwara.
Ninu atẹjade kan Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi lede niluu Ilọrin, lo ti sọ pe ọrọ ti Gani Adams sọ pe awọn agbebọn ati ajinigbe ti waa fori mu si ipinlẹ Kwara jẹ irọ ti ko si ootọ kan ninu rẹ. O ni ohun to yẹ ko sọ ni pe agbegbe Guusu ipinlẹ Kwara, ki i ṣe gbogbo ipinlẹ Kwara. O tẹsiwaju pe ileeṣẹ awọn ti ṣiṣẹ takun-takun, ti wọn si ti ni aṣeyọri nipa didoola ẹmi awọn ti wọn n jigbe, ti wọn si ti mu ọpọ awọn ajinigbe pẹlu. O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i kaaarẹ ninu ṣiṣe gbogbo ohun to yẹ lati mu ki alaafia maa jọba nipinlẹ Kwara.
Ajayi ni ileeṣẹ ọlọpaa n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn Fulani ati ẹgbẹ fijilante lawọn inu igbo ni tibu-tooro ipinlẹ Kwara lati ri i daju pe ko si awọn agbebọn ati awọn ajinigbe mọ jake-jado ipinlẹ ọhun. Bakan naa lo sọ pe Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Tuesday Assayomo, n lọ kaakiri gbogbo Guusu ipinlẹ Kwara lati ri awọn iroyin gba mu ni agbegbe naa nipa ibi ti eto aabo de duro lagbegbe ọhun, tawọn si ti ko awọn ẹṣọ alaabo si gbogbo ibi to yẹ nipinlẹ Kwara, ki aabo ẹmi ati dukia le wa fun gbogbo olugbe ipinlẹ naa.