Ijọba gbọdọ pẹjọ ta ko idajọ kootu Ko-tẹ-mi-lọrun to ni ki wọn tu Sọtitobirẹ silẹ-Ogele

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn ajafẹtọọ ọmọ eniyan nipinlẹ Ondo, Amofin Morakinyọ Ogele, ti ni ijọba ipinlẹ Ondo, labẹ akoso Gomina Rotimi Akeredolu, gbọdọ pẹjọ ta ko bi kootu ko-tẹ-mi-lọrun ṣe tu Oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ, Wolii Alfa Samuel Babatunde, silẹ ninu ọgba ẹwọn gbere ti wọn ju u si lori ọrọ ọmọ ọdun kan to sọnu ninu sọọsi rẹ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2019.

Agba Amofin ọhun ni ko si ani-ani pe ojuṣaaju wa ninu idajọ ti ile-ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun gbe kalẹ lọsẹ to kọja lọhun-un pẹlu bi igbimọ awọn oludajọ ọhun ṣe kuna patapata lati ṣiṣẹ lori ibi ti iṣẹlẹ ọmọ ọdun kan to sọnu naa ti kan Wolii Alfa gbọngbọn, ki wọn too pinnu lati paṣẹ titu u silẹ kuro ninu ọgba ẹwọn gbere ti ile-ẹjọ giga ju u si.

O ni igbesẹ to ba ofin Naijiria mu ni ile-ẹjọ giga gbe pẹlu bi wọn ṣe ran Sọtitobirẹ lẹwọn lori awọn ẹri aifojuri eyi ti kootu Ko-tẹ-mi-lọrun ta ko, ti wọn si tori rẹ fagi le idajọ ọhun.

O ni iwe ofin wa faaye gba ile-ẹjọ lati fiya jẹ ọdaran ti wọn ba fi awọn ẹri aifojuri gbe ẹsun ti wọn ba fi kan an lẹsẹ.

Gẹgẹ bii apẹẹrẹ, Ogele ni bi eeyan kan ba wa ọrẹ rẹ lọ sile ti nnkan si waa ṣẹlẹ si ẹni to wa lọ, awọn agbofinro lanfaani lati mu ẹni ọhun, ki wọn si ba a ṣẹjọ, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹri aridaju fun wọn pe oun lo ṣe ẹni naa leṣe, o ni eyi ni wọn n pe ni Ọkupaya Layabiliti (Occupier Liability) labẹ ofin.

O ni gbogbo ẹri lo fidi rẹ mulẹ pe Iya Gold gbe e wọ inu ṣọọsi Sọtitobirẹ to si forukọ rẹ silẹ ninu iwe ti wọn n kọ orukọ awọn ewe si, ti iru ọmọ bẹẹ ba waa sọnu, dandan ni fun ẹni to pe ara rẹ ni olori ijọ ọhun lati ṣawari rẹ lọnakọna tabi ko jẹjọ ọmọ to sọnu n’ile-ẹjọ ti ko ba ri i.

Ekeji, Ogele ni bii iwa iyanjẹ patapata ni bi wọn ṣe lu baba ọmọ to sọnu lalubami latari pe o n fẹhonu han lọjọ keji ti ọmọ rẹ sọnu

O ni tijọba ba fi kuna lati tete gbe igbesẹ to yẹ lasiko ti nnkan si n gbona lọwọ, o ṣee ṣe ki wọn pa ọrọ ọhun mọlẹ patapata ti ọmọ ti wọn n wa naa yoo si sọnu gbe lai ri ohunkohun ṣe si i.

Leave a Reply