Nitori ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara, ọmọ ‘Yahoo’ mọkandinlọgbọn ko sọwọ EFCC l’Ọffa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ yii, EFCC ko awọn ọmọ yahoo to n lọ bii mọkandinlọgbọn lawọn aaye ọtọọtọ niluu Ọffa, ijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara, fẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara atawọn ẹsun miiran to fara pẹ ẹ.

Ajọ naa sọ pe ọwọ tẹ wọn lẹyin ifinmu finlẹ awọn oṣiṣẹ ajọ naa ati itanilolobo lati ọwọ awọn araalu ti wọn si ri oniruuru awọn eroja kan gba lọwọ wọn to fi mọ awọn irinsẹ ti wọn fi n ṣe iṣẹ aburu wọn, lara awọn eroja ọhun ni ọkan-o-jọkan ẹrọ ibanisọrọ, laptop, atawọn ọkọ ayọkẹlẹ loriṣiiriṣii.

Orukọ awọn afurasi naa ni: Sikiru Mustapha, Abdulmartin Ọlawale, Gbọlahan Abdulamin, Abdulfawaz Olakanmi, Tunde Saheed, David Kọmọlafẹ, Adebayọ Ridwan, Oluwatobi Akinbọ, Fatimẹhin Kayọde, Ibrahim Zakariya, Ọlajide Moshood, Ikudaisi Adesọji, Habeeb Adeyẹmi, Hassan Akorede, Ahmed Quadri, Ọlanipẹkun Ibrahim, Ọlabisi Ọlọlade, Ahmed Akorede, Wasiu Adesina, Damilọla Samsudeen, Ọlaloye Damilare, Nathaniel Laoshe, Adeniyi Ọpẹyẹmi, Adebayọ Shahajudeen, Ṣẹgun Ajila, Kẹhinde Ọlaniyi ati Ibitowa Toyeeb. Titi di bi a ṣe n ko iroyin yii jọ, akolo ajọ EFCC ni awọn afurasi yii wa ti ajọ naa si ni lẹyin iwadii lẹkun-un-rẹrẹ gbogbo wọn aa foju ba ile-ẹjọ.

 

Leave a Reply