Itusilẹ ni Pasitọ Matthew loun fẹẹ ṣe f’ọmọ ijọ rẹ to fi fipa ba a lo pọ l’Ogijo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pasitọ ijọ Life and Power Bible Church,Ogijo, nipinlẹ Ogun, Matthew Ọladapọ, ti wa latimọle ọlọpaa nipinlẹ naa bayii. Ọmọ ijọ rẹ, ẹni ọdun mọkandinlogun(19) to fipa ba lo pọ ninu ṣọọṣi logunjọ, oṣu keji, ọdun 2022 yii lo gbe e debẹ.

Ọmọbinrin to fipa ba sun naa lo mẹjọ rẹ lọ si teṣan ọlọpaa Ogijo, oun lo ṣalaye fun wọn pe nigba toun kọkọ lọ si ṣọọṣi yii, Pasitọ Matthew sọ foun pe ọkọ ọrun n ba oun ja.

Ọmọbinrin naa tẹsiwaju pe pasitọ yii sọ foun pe iran ti Ọlọrun fi han oun ni pe ọkọ ọrun wa laye oun, bi ko ba si kuro nibẹ, ìṣòro aye oun ko ni i kuro. N lo ba ni itusilẹ loun yoo ṣe fun ọmọdebinrin yii ti ọkọ ọrun to n ba a ja yoo fi lọ.

Aawẹ ọlọjọ mẹta ati iṣọ oru mẹta ni Pasitọ Matthew sọ pe ọmọge ọhun gbọdọ gba ninu ṣọọṣi yii, yóò sì mu ẹgbẹrun kan Naira wa to ba n bọ fun itusilẹ naa, ati ororo ti wọn yoo fi ya a si mimọ.

Ṣugbọn lalẹ ọjọ akọkọ ti aawẹ ati adura naa yoo bẹrẹ gẹgẹ bi ọmọ ijọ naa ṣe wi, o ni Pasitọ Matthew Ọladapọ mu oun wọ yara kan ninu ọgba ṣọọṣi yii, nibẹ lo si ti paṣẹ pe koun bọ gbogbo aṣọ ara oun silẹ patapata, koun wa nihooho ọmọluabi, koun si sun sori aṣọ kan ti pasitọ yii ti tẹ silẹ ninu yara naa.

O loun ṣe bo ṣe wi, nigba naa lo si bẹrẹ si i fi ororo iyasimimọ toun ra wa pa oun lara. Ọmọge naa sọ pe Pasitọ Matthew kọwọ bọ abẹ oun nibi to ti n fi ororo ra oun lara, n loun ba yari pe ki lo le to bẹẹ, pasitọ yoo ṣe tun maa ‘finga’ abẹ oun nitori itusilẹ.

O ni ṣugbọn Pasitọ Matthew ko da oun loun mọ, Ibalopọ to fẹẹ ṣe labẹ oun ti wa lọkan rẹ, ara rẹ si ti le. Ọmọ naa sọ pe esi kan ti ọkunrin yii foun ko ju pe ko sọna mi-in ti wọn fi n ṣe itusilẹ ju ibalopọ lọ, afi koun ba a sun ni ọkọ ọrun fi le wabi kan gba lọ.

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ti ọmọ ko fẹẹ gba, Pasitọ fi agbara ọkunrin rin in mọlẹ, o fọwọ bo ọ lẹnu, o si ba a sun karakara.

Eyi ni ọmọ to fipa ba sun fi lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa, ti wọn fi lọọ gbe Pasitọ Matthew Ọladapọ.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ fawọn agbofinro, pasitọ yii jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọ ijọ oun sun, o ni ẹjọ oun naa kọ, ẹmi lo gbe oun wọ. Iru ẹmi to jẹ ṣaa, Pasitọ Matthew ko le sọ.

Wọn ti fi i pamọ sẹka to n ri si ṣiṣe ọmọde niṣekuṣe, yoo si foju bale-ẹjọ laipẹ, bawọn ọlọpaa ṣe wi.

Leave a Reply