Ọrẹoluwa Adedeji
Iyawo akọkọ ti ọkunrin makẹta ti ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Mercy Aigbe fẹ, Oluwafunṣọ Adeoti, ti sọrọ o. Obinrin naa ni irọ ni Kazeem Adeoti to ti fẹẹ kuro ni ọkọ oun bayii ati Mercy fi n lẹ owu loju pẹlu gbogbo ọrọ to n sọ nipa ajọṣepọ oun ati oṣere naa. O ni ọkunrin naa kan n tan ara rẹ jẹ lasan ni, oun ko si fẹ ko darukọ oun tabi ti awọn ọmọ oun si ọrọ to wa nilẹ naa.
Obinrin naa gbe ọrọ yii sori Instagraamu rẹ lẹyin ti ifọrọwerọ ti Mercy ṣe pẹlu Magasinni Media Room Hub jade sita.
O ni, ‘‘Mo fẹ ka jọọ ṣalaye ọrọ yii ko ye ara wa, ọrọ ti mo kọ yii da lori ifọrọwerọ kan ti Magasinni Media Room Hub ṣe pẹlu ọkunrin ti ko ni i pẹẹ di ‘ọkọ mi atijọ’ yii jẹ ọkan ninu awọn irọ oriṣiiriṣii to n pa. Mo fẹ kẹ ẹ mọ pe lodi si ohun ti Ọgbẹni Adeoti sọ, mi o gba, mi o si le gba ko ni iyawo keji ninu ajọṣepọ igbeyawo mi pẹlu rẹ.
‘‘Kazeem, mi o fẹ ki o maa pariwo igbeyawo to lalaafia, eyi ti o ko ni pẹlu emi Oluwafunṣọ Aṣiwaju Couture. Iwọ ati ale rẹ le maa tẹsiwaju ninu ohunkohun ti ẹ ba n ṣe. Ṣugbọn mi o fẹ ki o wa si ori ẹrọ ayelujaara ki o maa wọ emi atawọn ọmọ mi nilẹ pẹlu awọn iwa atiniloju ati iwa ọmọde ti o n hu, emi o ni i maa pẹlu ọbọ rẹ jawura ninu iwa omugọ ati oponu ti o n hu.
‘‘Ni ti iwọ Mercy, ka kuku sọ oju abẹ nikoo, ọrẹ ni wa, ṣugbọn itiju ati igbe aye gbajumọ ti o n gbe ko ni i jẹ ko o gba eleyii. Latigba ti ọmọ rẹ ti pe oṣu marun-un niwọ ati Kazeem ti n ba ara yin sun. Emi ni mo mu ọ mọ Kazeem gẹgẹ bii ọrẹ mi. Emi ni mo pe ọ, ti mo si tun pe iwọ ati ọkọ ti o n fẹ tẹlẹ funra mi wa sibi ajọdun ọjọọbi ogoji ọdun ọkọ mi. Ọrẹ timọtimọ mi ni ẹ nigba pipẹ sẹyin. Emi ni mo mu ọ sun mọ ẹbi mi nitori pe mo nifẹẹ rẹ, ṣugbọn o san an fun mi pẹlu biba ọkọ mi, Kazeem lajọṣepọ.
‘‘Iṣoro lo jẹ ninu igbeyawo mi fun ọpọlọpọ ọdun, inu mi si dun lati sọ fun ọ pe ibẹrẹ opin rẹ ni eyi. Mi o ṣe mọ o, Kazeem ti di tiẹ, ma a gbadun rẹ. Gẹgẹ bi mo ṣe sọ ninu ọrọ kan ti mo ti kọkọ kọ siwaju, ‘Ti eeyan ba padanu ẹni ti ko bọwọ fun un yan, ti ko si mọ riri ẹni jẹ ere nla, ki i ṣe adanu rara.
‘’Ẹ ṣeun, mo dupẹ.’’
Bi obinrin yii ṣe kọ ọrọ naa ree.