Olubadan tuntun: Mi o ni i ja awọn eeyan ilu Ibadan ati Naijiria kulẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Olubadan ilẹ Ibadan ti wọn ṣẹṣẹ gbe ọpa aṣẹ fun, Ọba Lekan Balogun, ti ṣeleri pe oun ko ni i ja awọn eeyan ilu Ibadan ati orileede Naijiria lapapọ kulẹ ni ipo ọba ti oun de yii. Bẹẹ lo beere fun atilẹyin awọn araalu lati le ṣaṣeyọri ni ipo tuntun naa.

O sọrọ naa gẹgẹ bii ọrọ akọsọ rẹ lẹyin ti Gomina Ṣeyi Makinde gbe ọpa asẹ fun un gẹgẹ bii Olubadan kejilelogoji nilẹ Ibadan.

Ọba Balogun ni, ‘‘Mo fẹẹ fi da yin loju pe mi o ni i ja ẹyin eeyan mi niluu Ibadan kulẹ, mi o si ni i ja gbogbo eeyan orileede Naijiria kulẹ. Ohun gbogbo to wa ni ikapa mi ni ma a ṣe lati mu ki ilẹ Ibadan tẹ siwaju. Mo si beere fun atilẹyin gbogbo yin lati le ṣe aṣeyọri.’’

Bakan naa lo dupẹ lọọ awọn gomina, awọn ọba alaye atawọn eeyan pataki pataki lawujọ to waa fi ijokoo yẹ ẹ si lasiko ayẹyẹ igbade yii.

Tilu tifọn ni ọba tuntun yii fi wọ inu gbọngan ti ayẹyẹ naa ti waye. Inu ofin nla kan ni ọba tuntun naa ko si. Bi gomina si ṣe fun un lọpaa aṣẹ ni wọn gbe ade ka ọba tuntun yii lori.

Leave a Reply