2023: Eyi nidi ti Ọṣinbajo, Ngige atawọn kan ko fi polongo ibo fun Tinubu – APC

Faith Adebọla

 Bi o ba nidii, obinrin ki i jẹ Kumolu. Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti ṣalaye idi ti lara awọn eekan eekan ẹgbẹ oṣelu naa bii Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Minisita fun ọrọ awọn oṣiṣe ati eto igbanisiṣẹ, Dokita Chris Ngige, Minisita tẹlẹri fun igbokegbodo ọkọ ati irinna, Rotimi Amaechi, ko fi kopa ninu eto ipolongo ibo fun aarẹ ẹgbẹ naa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, wọn ni ki i ṣe tija, ọrọ naa ni bo ṣe jẹ ni.

Adari eto iroyin ninu igbimọ ipolongo ibo funpo aarẹ wọn, Amofin agba Festus Keyamọ, lo tanmọlẹ sọrọ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ oṣu Kin-in-ni yii, o ni aṣẹ ti ọga Ọṣinbajo, iyẹn Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, pa fun un pe ko gbaju mọ ọrọ iṣakoso lasiko yii, tori iwọnba oṣu perete lo ku fun saa ọdun mẹjọ wọn, aṣẹ ọhun ni ko jẹ kawọn eeyan ri Ọṣinbajo bo ṣe yẹ nibi eto ipolongo ibo APC. Ni ti Igbakeji aarẹ, aṣẹ ti wọn pa fun un ni pe ko doju kọ iṣejọba. Tẹyin naa ba si kiye si i, Aarẹ ti n tẹle wa lọ sawọn ibi ta a ti ṣepolongo ibo.

 

O ni: “Rotimi Amaechi, iyẹn gomina ipinlẹ Rivers nigba kan, wa si eto ipolongo ibo ta a ṣe ni Adamawa ati Jos laipẹ yii, o ti bẹrẹ si i lọ sawọn rali (rally) wa kaakiri, ṣugbọn eyi to ba wu u lati lọ lo maa n lọ, ipinnu ara-ẹni ni.

“Bakan naa, Ngige, iyẹn Chris, to jẹ gomina ipinlẹ Anambra nigba kan, ko sọrọ ta ko ẹgbẹ wa, o kan jẹ pe o ti sọ p’oun ko ni i sọpọọti ẹgbẹ kankan, tabi oludije funpo aarẹ kankan ni toun ni, o loun fẹẹ duro ni danfo gedegbe, oun lo si mọ idi to fi ṣe ipinnu bẹẹ. Amọ ẹnikan ṣoṣo niyẹn jẹ laarin minisita bii mẹtalelogoji ta a ni.”

O waa kadii ọrọ rẹ pe: “Ko si ani-ani nibẹ, iṣọkan ati ajọṣepọ ẹgbẹ APC wa duro digbi ni, ko da bii ti ẹgbẹ PDP ti wọn ti fẹrẹ wogba tan.”

Tẹ o ba gbagbe, lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn eeyan ti n ṣakiyesi pe ẹkọ o ṣoju mimu laarin ẹgbẹ oṣelu APC, pẹlu bawọn agbaagba kan to yẹ ki wọn ṣugbaa oludije funpo aarẹ ẹgbẹ naa, Bọla Tinubu, ṣe n mọ eto ipolongo ibo rẹ loju tẹki. Lara wọn ni Ọṣinbajo, bẹẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ọkunrin naa n jade lọ sawọn ode ayẹyẹ ati ariya mi-in bii ayẹyẹ ọgọrun-un ọdun ti wọn ti da ileewe Baptist Boys High School, Abeokuta, silẹ, eyi ti Ọṣinbajo pesẹ si, to si kopa to jọju nibẹ.

Wọn loju ti ẹgbẹ APC fi gunyan eto ipolongo rẹ kọ lo fi n gbọbẹ lọdọ awọn eekan eekan ẹgbẹ naa lasiko yii, amọ Keyamo ti ni didun lọsan yoo so fawọn nigbẹyin o.

Leave a Reply